Àwọn àǹfàání tó wà nínú ewé efinrin tó yẹ kí o mọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ọkan lara awọn nnkan pataki ti Iṣẹda fi jinki iran eeyan ni ewe ati egbo.
B'awọn kan ṣe wa fun jijẹ ni wọn tun daa fun ilera gẹgẹ bii oogun, ewe efinrin si jẹ ọkan ninu wọn.
Oorun to yatọ la fi n da efinrin mọ, bẹẹ lo maa n ta lẹnu wẹrẹwẹrẹ.
Efinrin ni Yoruba n pe e, awọn Igbo n pe e ni Nchanwu, Hausa n pe e ni Daidoya, awọn onisayẹnsi si fun un ni 'Ocimum gratissimum.'
Diẹ lara awọn eroja aṣaraloore to wa ninu rẹ ni Fitamin A, Carbon, Iron, Phosphorus ati Calcium.
Wọ̀nyí ni díẹ̀ nínú àwọn àǹfààní tó wà lára efinrin
Ó dára fún ẹnu tó ń rùn
Gẹgẹ bi ẹka iwadii Phamapporach ṣe ṣalaye, ewe efinrin wulo lati ṣẹgun ẹnu to n run.
Bi eeyan ba n run igi efinrin bii pako, yoo gbogun ti ẹnu rirun, yoo si pa awọn kokoro aifojuri to le ṣakoba fun ẹnu.
Dídènà ibà
Ewe ibà ni awọn mi-in tun maa n pe efinrin, idi ni pe o n ṣiṣẹ gidi fun aisan iba, paapaa bi eeyan ba lo o pẹlu ewuro.
Eeyan le se e, o si le gbo ewe efinrin ti omi rẹ yoo fi jade.
Iwadii fi han pe awọn ti wọn ba maa n mu omi efinrin deede ki i tete dubulẹ aisan iba, nitori o maa n ro ara lagbara lati dena rẹ ni.
3) Ó kápá inú rírun àti ìgbọ̀nsẹ̀ gbuuru:
Ewe to maa n jẹ ki igbọnsẹ ṣiṣe dẹrun ni efinrin, bẹẹ lo maa n ti awọn ohun ti ara ko fẹ jade ninu ara eeyan.
Nipa idi eyi, igbẹ gbuuru ati idaamu inu yoo dopin bi eeyan ba mu efinrin.
4. Ó máa ń jẹ́ kí oúnjẹ tètè dà nínú:
Bi o ba ro efinrin gẹgẹ bi ẹfọ, tabi ti o se e bii ohun mimu tíì, o maa n ṣe iranlọwọ fun bi ounjẹ yoo ṣe tete da ninu. Inu rẹ ko ni i ṣe gbẹndu, gẹgẹ bi awọn dokita ṣe fidi rẹ mulẹ.
5) Efinrin ń ran ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ kó má bàà pọ̀jù:
Eroja Calcium ati Magnesium to wa ninu efinrin n ṣe iranwọ fun ṣuga to wa ninu ẹjẹ lati ma pọju.
Efinrin n ran eroja to n pese 'Insulin' fun ara lọwọ, o si tun n ran iṣẹ ọkan lọwọ pẹlu, nipa yiyọ ọra ti ko daa kuro ninu ara .
Ó dára fún ọ̀fìkìn.
Gẹgẹ bi akọsilẹ Pharmapproach ṣe wi, efinrin daa pupọ fun itọju otutu ati ọfikin.
Bi o ba jẹ efinrin tabi gbo ewe rẹ mu nigba ti imu rẹ ba di, wọn ni yoo jẹ ki oju opo ọna ọfun rẹ la, idẹra yoo si de ba ọ.
7) Lílé ẹ̀fọn jìnà réré:
Ja efinrin si apa ibi ti ẹfọn ba ti n kun si ọ leti, awọn yanmu-yanmu naa yoo kuro lọgan, gẹgẹ bi Pharmapproach ṣe fidi ẹ mulẹ.
Oorun to n ta sansan lara efinrin jẹ ohun ti ẹfọn ko nifẹẹ si, bẹẹ naa si ni ẹsinsin ati awọn kokoro yooku.
O le gbin efinrin sinu ikoko, ki o si gbe si agbegbe ti o ba maa n jokoo si tabi sun julọ.
8) Oògùn apakòkòrò:
Fun awọn kokoro to n so si ara eeyan, paapaa awọn eyi ti oyinbo n pe ni Fungai, iwadii fi han pe eroja Chloroform to wa lara efinrin maa n pa awọn kokoro yii.
9)Efinrin ń mú irun pọ̀ sí i:
Bi irun ori rẹ ba n re jẹ, iwadii kan ti Orafidiya et al (ati awon oluwadii miran) ṣe, fi han pe ororo kan ti a mọ so 'Ocimum' wa lara efinrin.
Eyi ni wọn lo maa n jẹ ki irun pọ si i bi eeyan ba n lo o.
10) Ó dára fún nǹkan ọkùnrin àti obìnrin :
Nitori 'arginine' ati eroja amino acid to wa ninu efinrin, awọn dokita ṣalaye pe o daa pupọ fun atọ ọkunrin lati kun pọpọ.
O si tun ni awọn nnkan kan to le mu ara ọkunrin maa dide bo ṣe yẹ.
Fun obinrin, ẹka iwadii Pharmappoach ṣalaye pe awọn kinni kan ti i ṣe 'anetol, boron' wa ninu efirin, eyi dara pupọ fun nnkan obinrin ti a mọ si estrogen.














