Ṣé nítorí èébú tí Portable bú àwọn ará Ibadan ni wọn ò ṣe jẹ́ kó kọrin lóde Taye Currency?

Portable Zazuu

Oríṣun àwòrán, Portable Zazuu/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn alakoso eto ariya ita gbangba ti gbajugbaja akọrin Fuji , Taye Currency gbe kalẹ niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo ti sọrọ lori idi pataki ti akọrin takasufee, Habib Okikiola tọpọ mọ si Portable ko ṣe kọrin nibẹ.

Ileeṣẹ naa ti wọn pe ni Jarule Entertainment sọ pe aabo ẹmi ati dukia awọn araalu, paapaa awọn ololufẹ Taye Cureency ṣe pataki pupọ, idi ree ti wọn ko fi gba Portable laaye lati kọrin nibi eto naa.

Wọn ni awọn kan to n binu si Portable to tun n pe ara rẹ ni Were Olorin ni wọn fẹẹ lo anfaani eto ariya naa lati fiya jẹ Portable, to si ṣee ṣe ki wahala ti wọn ko lero ṣẹlẹ.

"A ba kọmiṣanna ọlọpaa sọrọ, a si tọwọ bọwe adehun. Wọn fun wa ni eto aabo to peye nibi gbọngan ti a lo, ṣugbọn a tun ṣi gbọ pe awọn kan n beere nipa ibi ti Portable wa, ati ibi to de si niluu Ibadan," awọn alakoso naa sọ bẹẹ.

"Eyi lo jẹ ka pinnu wi pe Portable ko nii le kọrin fawọn ololufẹ rẹ. Oun nikan si ni ẹni ti ko kọrin ninu gbogbo awọn ti a fiwe pe wa sibẹ.

"Ohun to ba ni lọkan jẹ pupọ ni, ṣugbọn gẹgẹ bi ileeṣẹ to mọ iṣẹ rẹ daadaa, eto aabo jẹ ohun akọkọ. Idi si ree ti a ko fi jẹ ko ṣere.

Ki lo ṣẹlẹ tẹlẹ?

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọdun to kọja ni Portable bu ẹnu ẹtẹ lu ilu Ibadan ati awọn olugbe ibẹ, wi pe wọn ko ni ile to ni awọn ẹṣọ ile bii POP.

Portable sọrọ naa lasiko ti oun ati olori Alaafia ana, Damilọla jọ n tahun sira wọn lori ikanni ayelujara.

Eyi waye lẹyin ti tirela gba aarin ololufẹ mejeeji kọja.

Latigba ti Portable ti sọrọ yii la gbọ pe inu ti n bi awọn ọmọ ati olugbe ilu Ibadan kan, ti wọn si lawọn ko fẹẹ rii lati wa ṣere nibẹ.

Amọ a ko le sọ boya iṣẹlẹ naa lo mu ki awọn kan dọdẹ akọrin naa lọ si oju agbo.

Portable bẹbẹ

Portable Zazuu

Oríṣun àwòrán, Portable Zazuu/Facebook

Ṣugbọn ṣa, kete ti Taye Cureency pe Portable lati wa kọrin niluu Ibadan, nibi eto idaraya ita gbangba to gbe kalẹ, ni Portable gba ori ayelujara lọ lati rawọ ẹbẹ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe Taye Cureency ti fi owo ranṣẹ si oun lati wa kọrin niluu Ibadan, t'oun ko si gbọdọ ma yọju sibẹ, o ni ki awọn to n binu forijin oun fun aṣiṣe oun.

"Ẹyin ololufẹ mi, boya kẹẹ ma binu o. Taye Currency ti tẹ owo si mi, wọn ni pe awọn fẹẹ ṣe kọnsaati (concert) n'Ibadan, wi pe mo gbọdọ wa nibẹ.

"Ẹ dari jimi lori ọrọ oni POP yẹn, ṣe ẹ ṣi n binu ni? Ẹyin naa lẹ ni mi, ọmọ Ibadan naa ni mi. Ẹ foju aanu wo mi, ẹ daṣọ aṣiri bo mi, ki ẹ si da mi mọ ọmọ tọ."

Portable sọ pe owo ko si ṣee da pada, ode ariya naa ko ṣee ma lọ.