Golden Globes Awards, àmì ẹ̀yẹ fáwọn tó ṣe fíìmù wáyé, wo fíìmù àti àwọn òṣèré tayọ

Aworan Emilila Perez ati awọn mi-in nibi ayẹyẹ naa

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Aworan Emilila Perez ati awọn mi-in nibi ayẹyẹ naa.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lọjọ Aiku ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ Karun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 ni awọn elere ori itage, olorin to peregede, gba ami ẹyẹ idalọla nibi ayẹyẹ ami ẹyẹ agbaye ti a mọ si Golden Globe.

Ayẹyẹ gbigba ami ẹyẹ naa ti i ṣe ẹlẹkejilelọgọrin iru rẹ (82nd) ni i ṣe pẹlu awọn oyinbo.

California ni wọn ti tẹ pẹpẹ ti ọdun yii.

Wọnyi ni awọn ti wọn peregede naa ati bi wọn ṣe to wọn lẹsẹẹsẹ.

Eré

 Demi Moore ti wọn pe ni 'Popcorn actress' lọjọsi ree lasiko to gba ami ẹyẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Aworan Demi Moore ti wọn pe ni 'Popcorn actress' lọjọsi .

Ere kan ti wọn pe ni "The Brutalist" ni wọn fun ni ami ẹyẹ ere to peregede julọ.

Orin/awada (musical or comedy: "Emilia Perez"

Adari ere to peregede ju lọ: (Best director: Brady Corbet, "The Brutalist")

Oṣerekunrin to peregede julọ: (Best actor, drama: Adrien Brody, "The Brutalist")

Oṣerebinrin to peregedee julọ (Best actress, drama: Fernanda Torres, "I'm Still Here")

Oṣerekunrin lagbo orin/awada: Sebastian Stan, "A Different Man")

Ọṣerebinrin, orin/ awada: Demi Moore, "The Substance"

Amugbalẹgbẹẹ ọkunrin to daa ju (Best supporting actor: Kieran Culkin, "A Real Pain"

Amugbalẹgbẹ obinrin to daa julọ (Best supporting actress: Zoe Saldana, "Emilia Perez"

Itan to daa ju (Best screenplay:) Peter Straughan, "Conclave"

Ere ti ki i ṣe ti oyinbo to peregede ju (Best non-English language film) "Emilia Perez"

Orin ogidi to daa ju (Best original song: "El Mal" from "Emilia Perez"

Eyi to gba onka to daa ju (Best original score: Trent Reznor and Atticus Ross, "Challengers"

Alaṣeyọri lẹka sinima :Best cinematic and box office achievement: "Wicked"

Apilẹkọ ayaworan to daa ju lọ: Best animated feature: "Flow"

Amóhùnmáwòrán

Aworan Saldana, ọkan ninu awọn to gba ami ẹyẹ

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ere onipele to daa ju: "Shogun"

Oṣerekunrin elere ori itage to daa ju: Hiroyuki Sanada, "Shogun"

Oṣerebinrin elere ori itage to daa ju (Best drama actress:) Anna Sawai, "Shogun"

Orin ẹfẹ to daa ju: "Hacks"

Alawada ọkunrin to peregede julọ: (Best musical or comedy actor: Jeremy Allen White, "The Bear"

Alawada obinrin to daa julọ (Best musical or comedy actress): Jean Smart, "Hacks."

Ere onipele to daa julọ: Best limited series or TV movie: "Baby Reindeer"

Oṣere to daa julọ lẹka ere onipele: Best limited series or TV movie actor: Colin Farrell, "The Penguin"

Oṣerebinrin to daa julọ lẹka ere onipele (Best limited series or TV movie actress:) Jodie Foster, "True Detective: Night Country"

Alawada to ṣe daadaa ju lori amohumaworan:(Best performance in stand-up comedy on television): Ali Wong, "Ali Wong: Single Lady"

Aworan Richard Gadd nibi ayẹyẹ naa

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Aworan Richard Gadd nigba to n sọrọ lẹyin to gba ami ẹyẹ nibi ayẹyẹ naa.
Sebastian Stan fi ami ẹyẹ rẹ han pẹlu ẹrin ayọ.

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Sebastian Stan fi ami ẹyẹ rẹ han.

Àwọn òṣèré náà sọ̀rọ̀

Aworan Fernanda Torres, oun lo gba ami ẹyẹ elere ori itage to daa julọ.

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Aworan Fernanda Torres, oun lo gba ami ẹyẹ elere ori itage to daa julọ.

*Demi Moore: Oṣerebinrin to gba ami ẹyẹ oṣere to peregede julọ fun ipa to ko, sọ pe wọn ti figba kan bu oun ri pe elere oniguguru ni oun. (Popcorn actress).

Demi sọrọ naa lasiko to n gba ami ẹyẹ rẹ, pẹlu alaye pe ẹni to bu oun nigba naa sọ pe oun yoo maa ri iṣẹ ṣe ti yoo mu owo wọle, ṣugbọn oun ko le gba ami ẹyẹ.

Demi Moore ni ọrọ naa da omi tutu si oun lọkan nigba naa, ṣugbọn ami ẹyẹ yii ti ran oun leti pe iṣẹ ori ran oun loun n ṣe.

*Karla Sofía Gascón: Oṣere yii lo gba ami ẹyẹ alawada to daa ju.

O sọ nibi ayẹyẹ naa fun awọn eeyan pe, ''sọrọ soke, sọ pe emi gangan lemi, mi o ki n ṣe iru ẹni to o fẹ.''

* Kieran Culkin: Amugbalẹgbẹẹ oṣere to daa ju: Idanimọ akọkọ ti mo gba laye mi jẹ ti agbaye, nigba ti mo ṣi lọmọde.

Ni bayii, niṣe lo da bii ijade ọwọ alẹ to daa ju ti emi ati iyawo mi jọ lọ''

Culkin ti wọn fun ni ami ẹyẹ amugbalẹgbẹẹ to daa julọ fun ipa to ko ninu ere Real Pain.

Oríṣun àwòrán, Getty image