Ogbomoso Parapo: Bí ìgbẹ́jọ́ láàárín Soun àtàwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ ṣe lọ rèé

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó fi ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo ṣe ibùjókòó ti sún ìgbẹ́jọ́ èyí tó ń pè fún fífi òfin de Soun ìlú Ogbomoso, Oba Ghandi Olaoye láti má yan àwọn aláṣẹ fìdíẹ́ lé ọmọ ẹgbẹ́ Omo Ogbomoso Parapo Agbaye lórí.
Ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní, ọdún 2026 ni ilé ẹjọ́ náà sún ìgbẹ́jọ́ náà sí.
Adájọ́ N.E. Maha nígbà tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà lọ́jọ́ Kìíní, oṣù Kejìlá, ọdún 2025 sọ pé Oba Ghandi kò gbọdọ̀ tú àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ tó ti wà tẹ́lẹ̀ ká.
Ilé ẹjọ́ tún ṣe ìdádúró àwọn aláṣẹ fìdíẹ́ tí Ọba Ghandi yàn láti yé pe ara wọn ní aláṣẹ ẹgbẹ́ náà títí tí ìgbẹ́jọ́ fi máa wáyé ní oṣù Kìíní ọdún 2026.
Ṣáájú ni adélé alága Egbe Omo Ogbomoso Parapo Agbaye, Alhaji Yusuf Adetayi àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ méjì míì, Tolani Balogun àti Bukola Badmus ti wọ́ Ọba Ghandi, Ọ̀jọ̀gbọ́n Josiah Ajiboye àti ìgbìmọ̀ atófaratì ẹgbẹ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ fẹ́sùn pé wọ́n fẹ́ yan àwọn aláṣẹ mìíràn fún ẹgbẹ́ náà.
Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Soun ìlú Ogbomoso kéde, nínú oṣù Kẹsàn-án pé òun ti tú ìgbìmọ̀ àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ náà ká.
Bákan náà ló kéde yíyan Ọ̀jọ̀gbọ́n Josiah Ajiboye gẹ́gẹ́ alága fìdíẹ́ kó tó di pé wọ́n máa ṣe ètò ìdìbò láti yan àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ tuntun.
Ilé ẹjọ́ ní Ọba Ghandi kò gbọdọ̀ tún àwọn aláṣẹ náà ká àti pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Josiah Ajiboye kò gbọdọ̀ máa pe ara rẹ̀ ní alága, kí gbogbo nǹkan wà bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ títí ìgbẹ́jọ́ fi máa wá sópin.
Àmọ́ agbẹjọ́rò àwọn olùjẹ́jọ́ níbi ìgbẹ́jọ́ ọjọ́ Ajé náà sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn ti pé ẹjọ́ láti fi tako àṣẹ àti pé àwọn tún ti pe ẹjọ́ míì pé ilé ẹjọ́ náà kò láṣẹ láti gbọ́ ẹjọ́ náà.
Èyí ló mú kí wọ́n sún ìgbẹ́jọ́ di ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní, ọdún 2026 kí àwọn olùjẹ́jọ́ le fún àwọn tó pe ẹjọ́ ní ìwé ìpẹjọ́ lórí ẹ̀sùn tuntun náà.
Kí ló ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?
Nínú oṣù Kẹsàn-án ni awuyewuye mii tun ṣẹyọ niluu Ogbomoso lẹyin tawọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ alaṣẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye ti Soun ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye Orumogege Kẹta, tuka ke gbajare wi pe kabiesi naa ko lagbara lati tu igbimọ naa ka.
Ninu fọnran kan ti alukoro ẹgbẹ naa, Kọmureedi T.M. Balogun, alaga abẹle ẹgbẹ naa, Alhaji Iliasu Jamiu ati akọwe abẹle, Arabinrin Janet Akintoyinbo fi ranṣẹ sawọn ileeṣẹ iroyin ni wọn ti ṣalaye pe igbesẹ Ọba Olaoye tako iwe ofin ati ilana ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye.
Awọn oloye ẹgbẹ naa ko ṣai fidi rẹ mulẹ wi pe awọn ko tabuku tabi ṣe arifin si kabiyesi, ṣugbọn awọn n tẹle nnkan to wa ninu ofin ẹgbẹ naa ni.
Awọn oloye ẹgbẹ naa sọ fawọn ọmọbibi ilu Ogbomoso nile loko ati lẹyin odi wi pe awọn si wa nipo awọn gẹgẹ bii igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye.
Wọn ni igbesẹ Ọba Olaoye lati tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ ọhun ka ju agbara kabiyesi naa lọ.
Awọn oloye naa sọ ninu fọnran ti wọn fi sita naa wi pe ''Ọba ko ni agbara lati tu ẹgbẹ wa ka.
Ko si ninu iwe ofin ẹgbẹ wa bẹẹ, nitori naa, gbogbo awa oloye ẹgbẹ si wa ni ipo wa.
A ko fi eyi tabuku kabiyesi, bi ko ṣe wi pe a duro lori nnkan ti iwe ofin wa sọ lọ ni.''
Idi ti Soun Ọba Ghandi Olaoye fi tu igbimọ alaṣẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye ka
Kabiyesi Ọba Ghandi Olaoye to jẹ baba isalẹ ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye kede pe oun ti tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa ka.
Kabiyesi si gbe igbimọ fidihẹ kan dide eyi ti Ọjọgbọn Olusegun Ajiboye to jẹ akọwe agba ẹgbẹ to n ri si iforukọsilẹ awọn olukọọ, TRCN, tẹlẹ jẹ adari rẹ.
Igbimọ yii ni ori ade naa sọ pe yoo maa ṣakoso ẹgbẹ naa lọwọ yii.
Ọba Olaoye ni oun tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa ka fun atunto ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye ki ẹgbẹ naa le wa ni ibamu pẹlu eto idagbasoke ọlọdun mẹẹdọgbọn oun fun ilu Ogbomoso.
Amọ, ọpọ lo ti n sọ pe igbesẹ kabiyesi ko ṣẹyin ibaṣepọ ori ade naa ti ko dan mọran pẹlu awọn oloye ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye, eyi to jẹ ki ọpọ ninu wọn jinna si aafin.
Iroyin kan tiẹ fidi rẹ mulẹ wi pe aarẹ ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye tẹlẹ to doloogbe loṣu Kẹfa ọdun yii, Adajọ fẹyinti Afolabi Adeniran, kuna lati wa ojutuu si faakaja to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa.
Iroyin naa sọ pe eyi gan an lo jẹ ki kabiyesi gbe igbesẹ to gbe tori o dabi ẹni pe awọn kan ti fẹ ja ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye gba.
Lẹyin naa ni adele alaga ẹgbẹ atawọn mii gbe Ọba Ghandi atawọn meji mii lọ sile ẹjọ.















