Tinubu ní kí wọ́n dáàbò bo olùdíje sípò Ààrẹ Guinea-Bissau ní ọọ́físì ìjọba Naijiria lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba ológun

Aarẹ Tinubu ati ọkunrin naa to ni ki wọn daabo, Fernando Dias Da Costa

Oríṣun àwòrán, Samba BALDE / AFP via Getty Images)

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ ki wọn daabo bo Fernando Dias Da Costa, to jẹ oludije fun ipo Aarẹ Guinea Bissau ninu eto idibo orilẹede naa to waye loṣu to kọja.

Ninu lẹta kan ti minisita to n ri si ọrọ ilẹ okeere, Yusuf Tuggar, buwọlu, eyii to fi ṣọwọ si Aarẹ ẹgbẹ Ecowas, Omar Touray, Tuggar ni Aarẹ Naijiria ti paṣe pe ki wọn gbalejo ọkunrin naa ni ọọfisi ijọba Naijiria to wa lorilẹede naa, ki wọn si tun daabo bo nibẹ.

Lẹta naa sọ pe igbesẹ Tinubu ko ṣẹyin akitiyan rẹ lati daabo bo ọgbẹni Da Costa ki awọn kan ma baa gbẹmi rẹ.

Igbesẹ yi lo n waye lẹyin ti awọn ologun ditẹgbajọba lorilẹede naa lasiko ti awọn araalu n reti esi ibo Aarẹ ti wọn di loṣu to kọja.

Tinubu ni igbesẹ naa waye lati fi han pe digbi loun wa lẹyin ijọba awarawa ni Afrika ati ni gbogbo agbaye.

Fernando Dias lo n lewaju ninu awọn to gbe apoti ibo tako Aarẹ Umaro Sissoco ninu eto idibo naa, o si gbajumọ laarin ilu.

Ṣaaju ni ajọ eleto idibo orilẹede naa ti kọkọ kilọ faraalu pe ki wọn ma kede esi ibo kankan ayafi ti awọn funra awọn ba kede rẹ.

Asiko ti araalu n reti esi ibo Aarẹ naa lawọn ọkunrin kan ti wọn di ihamọra ogun fi panpẹ ofin mu Aarẹ Guinea-Bissau, Umaro Sissoco Embaló, eyii to farajọ iditẹgbajọba.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ kẹta lẹyin idibo naa ti wọn ti kọkọ yọ ẹni to n lewaju ninu awọn alatako Aarẹ ni iṣẹlẹ ọhun waye.

Awọn ologun kede lori ẹrọ amohunmaworan pe awọn ni yoo maa ṣakoso orilẹede naa titi di igba ti awọn yoo kede.

'Magomago' ṣẹlẹ nibẹ

Ẹwẹ, Aarẹ Naijiria Naijiria tẹlẹ, Goodluck Jonathan wa lara awọn to kọkọ ha si orilẹede naa lẹyin ti ologun gbajọa nibẹ.

Amọ lẹyin iṣẹlẹ naa ni baalu ileesẹ Aarẹ Ivory Coast gbe Jonathan pada wa si Naijiria lai farapa

Nigba to de, Jonathan sọ pe wọn gbọdọ kede orukọ ẹni to jawe olubori ninu idibo ọhun.

O ni asiko ti Aarẹ Guinea-Bissau, Embalo n ba awọn akọroyin sọrọ lọwọ ni iditẹgbajọba naa waye, amọ kii ṣe bẹẹ ni iditẹgbajọba ṣe maa n waye, to si mu ifura lọwọ

O sọ pe "Ohun to waye ni Guinea-Bissau kii ṣe iditẹgbajọba, nitori Aarẹ funra rẹ lo kede iditẹgbajọba naa faraye… bẹẹ kọ ni iditẹgbajọba ṣe maa n waye.

"Asiko ti iṣẹle naa n lọ lọwọ ni Embalo funra rẹ n ba awọn ileeṣẹ iroyin agbaye sọrọ lori aago pe wọn ti fi ṣikun ofin mu oun."