Wo gbogbo ohun to yẹ kí o mọ̀ nípa ìdíje Afcon 2025

Awọn agbabọọlu Ivory Coast meji, Simon Adingra ati Max-Alain Gradel di ife ẹyẹ Afcon mu pẹlu idunnu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Loṣu kejila yii lawọn agbabọọlu ilẹ Afirika yoo peju si orilẹede Morocco nibi ti idije Afcon 2025 yoo ti waye lati oṣu Kejila yii si oṣu Kinni ọdun 2026.

Ojọ Aiku ọjọ kọkanlelogun oṣu yii ni Morocco to n gbalejo idije naa yoo maa koju Comoros ni papa iṣere Prince Moulay Abdellah niluu Rabat ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ idije naa.

Oju wa lara Morocco gẹgẹ bii olugbalejo ati ẹgbẹ agbabọọlu Afirika to gbewọn julọ ninu oṣunwọn FIFA pẹlu ipo kọkanla ti wọn wa, ti wọn o si ti gba ife Afcon lati ọdun 1976 ti wọn ti gba a kẹyin.

Ẹwẹ, Mohamed Salah, ti ko tii gba ife ẹyẹ Afcon ri naa yoo maa gbiyanju lati gba a pẹlu Egypt lọtẹ yii.

Amọ, awọn ipenija wo ni Salah ati Egypt yoo koju? BBC ṣe atupalẹ gbogbo nnkan to yẹ ki o mọ nipa idije Afcon 2025 tii ṣe ẹlẹẹkarundinloji iru rẹ.

Awọri isọri ẹgbẹ agbabọọlu ni idije Afcon 2025

Wọn pin ẹgbẹ agbabọọlu mẹrinlelogun si isọri mẹfa, eyi ti isọri kọọkan ni ikọ agbabọọlu mérin mẹrin.

Wọnyi lawọn isọri ẹgbẹ agbabọọlu to n kopa ninu idije Afcon 2025:

Isọri A: Morocco, Mali, Zambia, Comoros.

Isọri B: Egypt, South Africa, Angola, Zimbabwe.

Isọri C: Nigeria, Tunisia, Uganda, Tanzania.

Isọri D: Senegal, DR Congo, Benin, Botswana.

Isọri E: Algeria, Burkina Faso, Equatorial Guinea, Sudan.

Isọri F: Ivory Coast, Cameroon, Gabon, Mozambique.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu to ba ṣe ipo kinni ati ikeji lawọn isọri kọọkan atawọn mẹrin to ba ṣe daadaa julọ ninu awọn to ṣe ipo kẹta ni gbogbo isọri ni yoo pegede fun isọri kọmẹsẹ ọ yọ ẹlẹnimẹrindinlogun.

Aago tawọn ifẹsẹwọnsẹ ni Afcon 2025 yoo maa bẹrẹ

Aago meje GMT ni ifẹsẹwọnsẹ akọkọ laaarin Morocco ati Comoros yoo bẹrẹ lọjọ Aiku ọjọ kọkanlelogun oṣu Kejila yii.

Bayii ni gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ni ipele akọkọ yoo maa waye titi di ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kejila.

Awọn akoko tawọn ifẹsẹwọnsẹ ọhun yoo maa waye ni 12:30 pm, 15:00 pm, 17:30 pm ati 8pm.

NI bii aago mẹrin irọlẹ si meje ni ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba ipele akọkọ yoo maa waye.

Ifẹsẹwọnsẹ ti ipele ko mẹsẹ ọ yọ naa yoo maa waye ni bii aago mẹrin irọlẹ si meje.

Ọjọ kedidinlogun oṣu Kinni ni ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije Afcon yoo waye ni aago meje irọlẹ.

Awọn papa iṣere Afcon 2025

Ita papa iṣere Prince Moulay Abdellah nibi ti ifẹsẹwọnsẹ akọkọ idije Afcon 2025 yoo ti waye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹde Morocco ti nawo gọbọi lati tun awọn papa iṣere wọn ṣe lati le gbalejo idije Afcon 2025 ati lati le gbalejo idije FIFA World Cup 2030 pẹlu Spain.

Papa iṣere mẹsan ni ilu mẹfa ni Morocco yoo lo fun idije Afcon 2025.

  • Papa iṣere Prince Moulay Abdellah, Rabat
  • Papa iṣere Olympics Sportif Prince Moulay Abdellah
  • Papa iṣere Sportif Prince Heritier Moulay El Hassan, Rabat
  • Papa iṣere Stade El Barid, Rabat
  • Papa iṣere Grande Stade d'Agadir
  • Papa iṣere Sportif de Fes, Fes
  • Papa iṣere Stade de Marrakech, Marrakech
  • Papa i'sere Mohammed V, Casablanca
  • Papa iṣere Stade de Tangier, Tangier

Igba wo lawọn agbabọọlu yoo de si idije Afcon?

Agbabọọlu Cameroon, Bryan Mbeumo ati akẹgbẹ rẹ ni Manchester Unitred, Bruno Fernandes n yayọ goolu ti Mbeumo gba sawọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ FIFA to n ṣakoso ere bọọlu lagbaaye ti kede pe ọjọ kẹẹdogun oṣu Kejila yii lawọn ẹgbẹ agbabọọlu gbọdọ fi awọn agbabọọlu ilẹ Afiika silẹ lati lọ ṣoju orilẹede wọn ninu idije Afcon 2025.

Akọnimọọgba Mali, Tom Saintfiet, fi aidunnu rẹ si eto yii, o ni o le ṣakoba fun igbaradi idije naa.

Koda, awọn ikọ agbabọọlu mii tun le bawọn orilẹede awọn agbabọọlu wọn sọrọ lati jẹ ki wọn si gbabọọlu fun ikọ wọn jọ ọjọ ti FIFa kede lọ.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu to ṣee ṣe ki wọn gba ife ẹyẹ Afcon 2025

Awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Morocco n dunnu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ṣee ṣe ki Morocco to ti jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ mejidinlogun lera wọn gba ife ẹyẹ naa.

Fun bi ogun oṣu bayii ni Morocco ti n fakọyọ ninu ere bọọlu ti wọn si ti gba aadọta goolu sawọn.

Senegal ni ẹgbẹ agbabọọlu mii to le gba ife ẹyẹ naa, awọn lo gbami ẹyẹ Afcon yii lódun 2021.

Bo tilẹ jé pe Brazil lu Senegal ninu ere bọọlu ọlọọrẹ sọọrẹ ti wọn jọ gba loṣu to lọ, Senegal naa lu Kenya lalubami pélu goolu méjọ sodo.

Algeria, Egypt atiIvory Coast ti ife naa wa lọwọ naa ko gbẹyin rara, gbogbo wọn lo fakọyọ ninu idije ati pegede fun FIFA 2026 World Cup.

Pẹlu bi agbabọọlu meje ọtọọtọ ti gbami ẹyẹ naa ni igba mẹjọ ti idije ọhun waye sẹyin, o ṣee ṣe ki ọpọ iyalẹnu tun ṣẹlẹ ninu idije Afcon 2025.

Bi awọn ifẹsẹwọnsẹ Afcon 2025 yoo ṣe lọ ree

Bọọlu ti wọn n pe ni Itri ni wọn yoo lo ni idije Afcon 2025

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bọọlu ti wọn n pe ni Itri ni wọn yoo lo ni idije Afcon 2025
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Akoko GMT ni gbogbo akoko yii

Ọjọ Aiku, 21-12-25

Isọri A: Morocco vs Comoros, Prince Moulay Abdellah Stadium, Rabat (19:00)

Ọjọ Aje, 22-12-25

Isọri A: Mali vs Zambia, Stade Mohammed V, Casablanca (14:00)

Isọri B: South Africa vs Angola, Grande Stade de Marrakech, Marrakech (17:00)

Isọri B: Egypt vs Zimbabwe, Grande Stade d'Agadir, Agadir (20:00)

Ọjọ Iṣẹgun, 23-12-25

Isọri D: Senegal vs Botswana, Grande Stade de Tangier, Tangier (12:30)

Isọri D: DR Congo vs Benin, Stade El Barid, Rabat (15:00)

Isọri C: Nigeria vs Tanzania, Complexe Sportif de Fes, Fes (17:30)

Isọri C: Tunisia vs Uganda, Olympic Stadium, Rabat (20:00)

Ọjọru, 24-12-25

Isọri E: Burkina Faso vs Equatorial Guinea, Casablanca (12:30)

Isọri E: Algeria vs Sudan, Complexe Sportif Prince Heritier Moulay El Hassan, Rabat (15:00)

Isọri F: Ivory Coast vs Mozambique, Marrakech (17:30)

Isọri F: Cameroon vs Gabon, Agadir (20:00)

Ọjọ Ẹti, 26-12-25

Isọri B: Angola vs Zimbabwe, Marrakech (12:30)

Isọri B: Egypt vs South Africa, Agadir (15:00)

Isọri A: Zambia vs Comoros, Casablanca (17:30)

Iṣọri A: Morocco vs Mali, Prince Moulay Abdellah Stadium, Rabat (20:00)

Ọjọ Abaméta, 27-12-25

Iṣọri D: Benin vs Botswana, Olympic Stadium, Rabat (12:30)

Iṣọri D: Senegal vs DR Congo, Tangier (15:00)

Iṣọri C: Uganda vs Tanzania, Stade El Barid, Rabat (17:30)

Iṣọri C: Nigeria vs Tunisia, Fes (20:00)

Ọjọ Aiku, 28-12-25

Iṣọri F: Gabon vs Mozambique, Agadir (12:30)

Iṣọri E: Equatorial Guinea vs Sudan, Casablanca (15:00)

Iṣọri E: Algeria vs Burkina Faso, Complexe Sportif Prince Heritier Moulay El Hassan, Rabat (17:30)

Iṣọri F: Ivory Coast vs Cameroon, Marrakech (20:00)

Agbabọọlu Senegal, Sadio Mane lori papa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ Aje, 29-12-25

Isọri B: Angola vs Egypt, Agadir (16:00)

Isọri B: Zimbabwe vs South Africa, Marrakech (16:00)

Isọri A: Comoros vs Mali, Casablanca (19:00)

Isọri A: Zambia vs Morocco, Prince Moulay Abdellah Stadium, Rabat (19:00)

Ọjọ Iṣegun, 30-12-25

Isọri C: Tanzania vs Tunisia, Olympic Stadium, Rabat (16:00)

Isọri C: Uganda vs Nigeria, Fes (16:00)

Isọri D: Benin vs Senegal, Tangier (19:00)

Isọri D: Botswana vs DR Congo, Stade El Barid, Rabat (19:00)

Ọjọru, 31-12-25

Isọri E: Equatorial Guinea vs Algeria, Complexe Sportif Prince Heritier Moulay El Hassan, Rabat (16:00)

Isọri E: Sudan vs Burkina Faso, Casablanca (16:00)

Isọri F: Gabon vs Ivory Coast, Marrakech (19:00)

Isọri F: Mozambique vs Cameroon, Agadir (19:00)

Bi ifẹsẹwọnsẹ Ipele keji idije Afcon 2025 yoo ṣe lọ

Agbabọọlu Equatorial Guinea, Emilio Nsue, lo gbamọ ẹyẹ agbabọọlu to gba goolu sawọn julọ ni idije idije Afcon 2023

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ Abaméta, 3-01-25

SR1: ẹni to bori isọri D v ẹni to ṣe ipo kẹta ni isọri B/E/F, Tangier (16:00)

SR2: ikọ to ṣe ipo keji ni isọri A v ikọ to ṣe ipo keji ni isọri C, Casablanca (19:00)

Ọjọ Aiku, 4-12-25

SR3: Ikọ to bori isọri A v ikọ to ṣe ipo kẹta ni isọri C/D/E, Prince Moulay Abdellah Stadium, Rabat (16:00)

SR4: ikọ to ṣe ipo keji ni isọri B v ikọ to ṣe ipo keji ni isọri F, Stade El Barid, Rabat (19:00)

Ọjọ Aje, 5-01-26

SR5: ẹni to bori isọri B vs ẹni to ṣe ipo kẹta ni isọri A/C/D, Agadir (16:00)

SR6: ẹni to bori isọri C vs ẹni to ṣe ipo kẹta ni isọri A/B/F, Fes (19:00)

Ọjọ Iṣẹgun, 6-01-26

SR7: ẹni to bori isọri E vs ikọ to ṣe ipo keji ni isọri D, Complexe Sportif Prince Heretier Moulay El Hassan, Rabat (16:00)

SR8: ẹni to bori isọri F vs ikọ to ṣe ipo keji ni isọri E, Marrakech (19:00)

Ipele komẹsẹ ọ yọ ẹlẹni mẹjọ ni idije Afcon 2025

Aṣọle South Africa, Ronwen Williams, lori papa ninu idije Afon 2023

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ Ẹti , 9-01-25

QF1: Ikọ to bori ni SR2 vs Ikọ to bori ni SR1, Tangier (16:00)

QF2: Ikọ to bori ni SR4 vs Ikọ to bori ni SR3, Prince Moulay Abdellah Stadium, Rabat (19:00)

Ọjọ Abaméta, 10-01-25

QF3: Ikọ to bori ni SR7 vs Ikọ to bori ni SR6, Marrakech (16:00)

QF4: Ikọ to bori ni SR5 vs Ikọ to bori ni SR8, Agadir (19:00)

Ipele to kangun si aṣekagba

Ọjọru, 14-01-25

SF1: Ikọ to bori ni QF1 vs Ikọ to bori ni QF4, Tangier (17:00)

SF2: Ikọ to bori ni QF3 vs Ikọ to bori ni QF2, Prince Moulay Abdellah Stadium, Rabat (20:00)

Idije fun ipo kẹta

Ọjọ Abamẹta, 17-01-26

SF1 vs SF2, Casablanca (16:00)

Balogun ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria tẹlẹ, William Troost-Ekong, ninu idije Afcon 2023

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ifẹsẹwọnsẹ Afcon 2025

Ọjọ Aiku, 18-01-26

Ikọ to bori ni SF1 vs Ikọ to bori ni SF2, Prince Moulay Abdellah Stadium, Rabat (19:00)