Ìjọba àpapọ̀ kéde ìdáǹdè akẹ́kọ̀ọ́ 100 nínú àwọn tí wọ́n jí gbé ní St Mary Catholic, Papiri

Ọgọrun-un kan akẹkọọ (100) ninu awọn to le ni ọọdunrun ti awọn ajinigbe ji gbe nile ẹkọ St Mary's Catholic School, Papiri, nipinlẹ Niger ni wọn ti gba itusilẹ kuro ni akata awọn ajinigbe naa bayii.
Ọjọ Aiku ana ni iroyin naa gbode kari ayelujara, pe ijọba apapọ ti ri ọgọrun-un akẹkọọ gba kalẹ loko ajinigbe ninu awọn ti wọn gbe lọ nile ẹkọ naa.
Bakan naa ni Alaga ajọ Christian Association of Nigeria (CAN), ẹka ti ipinlẹ Niger, Biṣọọbu Bulus Dauwa Yohanna, ati Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa; Adamu Abdullahi Elleman, fidi rẹ mulẹ fun BBC.
Awọn eeyan naa sọ pe awọn ẹṣọ alaabo ti fidi ẹ mulẹ, pe akẹkọọ ọgọrun-un kan ti gba ominira.
Wọn fi kun un pe awọn gbọ ọrọ naa lati ọfiisi Oludamọran pataki fun ijọba lori eto aabo, Nuhu Ribadu.
Ati pe lati oni ọjọ Aje ni wọn yoo ti maa yọnda wọn fun awọn obi wọn ni ipele-ipele.
Ọsẹ to kọja ni Nuhu Ribadu, ṣabẹwo si Papiri, ṣepade pẹlu awọn aṣoju CAN nipinlẹ Niger.
Nibi ipade naa lo ti ṣeleri pe awọn to wa nigbekun ko ni i pẹ gba itusilẹ.
O ni wọn yoo si pada si ọdọ awọn ẹbi wọn laipẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni awọn ajinigbe yabo ile ẹkọ St Mary's Catholic School, ti wọn ji akẹkọọ ati awọn olukọ lọ.
Apapọ awọn ti wọn ji gbe naa jẹ 315 bi iroyin ṣe fidi ẹ mulẹ.
Lẹyin naa ni iroyin gbode pe 51 ninu wọn ti raye sa mọ awọn ajinigbe naa lọwọ ninu oṣu kan naa ti wọn ji wọn gbe.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufoma/ BBC
Èèyàn mélòó ló ṣẹ́kù sígbèkùn ajínigbé?
Ninu iwe to ṣafihan orukọ awọn akẹkọọ ati olukọ ti ajinigbe ji gbe naa, eyi ti ẹka ṣọọṣi Katoliiki Kotangora (Catholic Diocese of Kontagora) fi sita lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025, eeyan 265 ni wọn lo ṣẹku si akata awọn ajinigbe nigba naa.
Ṣugbọn pẹlu ọgọrun-un ti wọn ni wọn ti gba itusilẹ bayii, o ṣẹku eeyan 165 ni ahamọ ajinigbe ninu awon ti wọn gbe lọ ni St Mary's Catholic School, Papiri, bayii.
Ṣaaju eyi ni wọn ti ṣe onka awọn ti wọn ji gbe naa, pẹlu alaye pe olukọ marun-un, awọn oṣiṣẹ ti ki i ṣe olukọ, meje, akẹkọọ ile ẹkọ girama mẹrinla, ati 239 lati ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ati jẹle-o-sinmi .
Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa kan, Abilekọ Sunday, ṣalaye fun BBC pe ọmọ ẹgbọn oun meji ni wọn ji gbe lọjọ naa.
"Ọmọ mẹrin lo ni nile ẹkọ naa, wọn ji meji lọ loru ninu wọn. Ọkan wa ni iwe kẹfa, ikeji wa ni iwe kẹta. "
''Inu igbo lo ni iya awọn ọmọ naa wọ lọ, to n sunkun kikoro lai dakẹ.''
Ijinigbe nile ẹkọ yii lo waye lẹyin ọjọ diẹ ti awọn ajinigbe yabo ile ẹkọ awọn ọmọbinrin ni Kebbi, ti wọn ji ọpọ ninu wọn gbe lọ.
Lẹyin ọjọ diẹ lakata awọn ajinigbe naa si ni ijọba apapọ kede pe awọn ti ri wọn gba wale pẹlu ilana ọrọ ajọsọ ti ko ni jagidijagan ninu (Non Kinectic).














