"Wọ́n pa bàbá-bàbá mi àti bàbá ìyàwó mi, bó ṣe wù wọ́n ni wọn ǹ pa wa, n kò fẹ́ kí wọn fi okùn fún mi lọ́rùn pa, wọ̀n fẹ́ pa aláwọ̀ funfun rẹ́ ní South Africa"

Àkọlé fídíò, White South African
    • Author, Claire Mawisa
    • Role, BBC Africa Eye
    • Reporting from, Free State
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Agbẹ kan, Marthinus to wọ aṣọ otutu alawọ aro
Àkọlé àwòrán, Marthinus n bẹbẹ lati lọ si Amẹrika nitori ibẹru

Nigba ti Marthinus, to jẹ agbẹ n ṣalaye ipo to wa pẹlu odi onirin to yi ka pẹlu ọpọ kamẹra to n wo o, o ni ṣe lo da bii pe inu ẹwọn loun wa.

O ni "O daa bii pe inu ẹwọn ni mo wa; wọn le wa pa wa ti wọn ba fẹ. Amọ yoo gba wọn ni akoko diẹ ki wọn to ri mi pa."

Ibẹru ikọluu yii lo mu ibẹrubojo ba ọkan ọmọ South Afrika naa to jẹ agbẹ alawọ funfun ti oun ati iyawo atawọn ọmọ wọn obinrin meji sa pamọ. Ko fẹ sọ orukọ rẹ ni kikun fun wa.

Inu oko ni wọn pa baba-baba rẹ ati baba-baba iyawo rẹ si.

Irinajo wakati meji pere si ibi to n gbe ni wọn pa ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Brendan Horner si. Niṣe ni wọn so oloogbe naa mọ opo kan toun ti okun lọrun rẹ.

O ni ọgbọn ọlọgbọn ni kii jẹ ka pe agbalagba ni were, nitori naa oun ko ni kawọ gbera ki irufẹ nnkan bẹẹ ṣẹlẹ si oun.

Ninu oṣu Kẹji ọdun yii, oun ati mọlẹbi rẹ kọwe ẹbẹ silẹ Amẹrika lati ṣatipo nibẹ.

O ni "mo ṣetan lati ṣatipo nibẹ fun igbeaye rere iyawo atawọn ọmọ mi nitori mi o fẹ ki wọn pa wọn ki wọn si gbe oku wọn kọ ori igi.

"Inu ewu nla ni awa ọmọ South Afrika alawọ funfun wa lọwọ yii."

Awọn agutan ninu oko atawọn oluṣọ wọn
Àkọlé àwòrán, Marthinus yoo ni lati fi oko rẹ silẹ to ba lọ silẹ Amẹrika

Iroyin ni ẹgbẹgbẹrun awọn ọmọ South Afrika alawọ funfun ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Yuroopu to ti wa nibẹ fun ọpọ ọdun lo ti n kọwe lati lọ ṣatipo l'Amẹrika.

Eyii bẹrẹ lati igba ti Aarẹ Donald Trump ti kede pe wọn le ṣe bẹẹ lati ibẹrẹ ọdun yii.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba Amẹrika sọ pe oun yoo din awọn atipo toun gba wọle ku lọdọdun lati 125,000 si 7,500, Trump ko fi ọrọ awọn alawọ funfun South Afrika ṣere.

Iwe ijọba ilẹ kan sọ pe awọn alawọ funfun South Afrika ni wọn yoo gba wọle bo tilẹ jẹ pe wọn yoo gba awọn eeyan ilẹ mii ti iya n jẹ lorilẹede wọn wọle pẹlu.

Marthinu ni ọrọ naa jẹ ọna abayọ fun oun ati mọlẹbi oun.

O ni "mo maa fi gbogbo aye mi silẹ ki awọn ọmọ ati iyawo mi le wa ni alaafia.

Ojojumọ ni iwa ọdaran n le kenka si ni South Afrika.

Atẹjade ijọba ilẹ naa fi han pe ni ibẹrẹ ọdun yii, eeyan 63 ni wọn n ṣekupa lojojumọ nibẹ.

Bo tilẹ jẹ pe o din diẹ ju ti ọdun 2024 lọ, South Afrika wa lara orilẹede ti wọn ti n gbẹmi awọn eeyan julọ lagbaye.

Thabo Makopo duro ninu oko rẹ pẹlu igo kan lọwọ rẹ
Àkọlé àwòrán, Agbẹ yii, Thabo Makopo ni ẹru ikọlu awọn ọdaran n ba oun naa

Awọn agbẹ alawọ dudu naa ko gbẹyin.

Niluu kan ti wọn n pe ni Ficksburg, agbẹ kan nibẹ, Thabo Makopo ni oko ti iwọn rẹ jẹ 237 eeka nibi to ti n sin agutan ati maalu.

O ni ọpọ igba lawọn kọlọrọsi ẹda maa n kọlu oun nibẹ.

Ọkunrin naa ṣalaye fun BBC pe "ọdọ langba ni wọn, wọn ni ohun ija oloro lọwọ wọn, wọn si buru jọjọ. Dandan ni wọn maa ko ohun ọsin lọ yala wọn padanu ẹmi wọn ni o tabi iwọ funra rẹ padanu ẹmi rẹ si wọn lọwọ."

Thabo gbagbọ pe gbogbo agbẹ to wa lagbegbe naa ni ẹmi wọn wa ninu ewu yala agbẹ ọhun jẹ alawọ dudu tabi alawọ funfun.

O ni "Gbogbo wa ni wọn n kọlu. Wọn le kọlu mi lonii gan paapaa – ko si ẹni ti ko le ṣẹlẹ si."

Bo tilẹ jẹ wọn n fi awọn ikọlu naa to ọlọpaa leti a gbọ pe awọn ọlọpaa naa ko ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ.

Lọwọ yii, pupọ awọn eeyan agbegbe naa lo ti n lo awọn ẹṣọ alaabo aladani bayii.

Awọn ẹṣọ alaabo aladani ilẹ naa to 630,000, eyii to pọ ju aapọ ọlọpaa atawọn ọmọ ogun orilẹede naa lọ.

Agbẹ alawọ funfun Morgan Barrett driving joko pẹlu fila lori rẹ
Àkọlé àwòrán, Morgan Barrett ni oun ko gbagbọ wọn fẹ pa awọn alawọ funfun rẹ nibẹ
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọpọ awọn agbẹ mii bii Morgan Barrett, to jẹ alawọ funfun lo gba ẹṣo alaabo funra wọn.

Iwọn oko rẹ to ẹgbẹrun meji eeka to ti wa ninu mọlẹbi rẹ fun iran mẹfa.

Ojojumọ lo maa n kaakiri inu oko naa ninu ọkọ rẹ fun aabo.

Lọsẹ diẹ sẹyin ni wọn ji maalu mẹfa ninu oko rẹ.

O ni "o le pe ọlọpaa ko jẹ lẹyin wakati meji si mẹta ni wọn a ṣẹṣẹ de lẹyin ti awọn ole naa a ti salọ."

Thabo sọ pe oun ko gbagbọ pe nitori awọ oun ni wọn ṣe n kọlu oko oun.

"Mi o gba bẹẹ rara pe awọn alawọ funfun nikan ni wọn n kọlu lagbegbe yii.

"Ti wọn ba gbagbọ pe alawọ dudu ni 20,000 rand ($1,200; £880) lọwọ, wọn maa kọlu u bi wọn ṣe maa kọlu alawọ funfun to ni irufẹ owo bẹẹ lapamọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ti wọn n sọ pe awọn kan fẹ pa ẹya alawọ funfun rẹ ni South Afrika ko mọ itumọ pe wọn n pa odidi ẹya rẹ.

"Ohun to n ṣẹlẹ ni Rwanda ni wọn n pe ni pipa ẹya rẹ. Ohun to n ṣẹlẹ si awọn agbẹ alawọ nibi funfun buru jai amọ a ko le pe e ni pipa ẹya rẹ."

Trump ti sọ pe wọn n pa ẹya alawọ funfun rẹ ni South Afrika, ọrẹ rẹ naa, Elon Musk ni awọn oloṣelu ilẹ ọhun n ran awọn eeyan ibi lọwọ lati pa ẹya alawọ funfun rẹ.

Amọ ijọba orilẹede naa ti sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ.

Minisita fun ọrọ ọlọpaa Senzo Mchunu sọ pe laarin ọdun 2024 si 2025 eeyan mejidinlogun ni wọn pa sinu oko wọn, mẹrindinlogun lo jẹ alawọ dudu nigba ti awọn meji to ku jẹ alawọ funfun.

Fun ọpọ ọdun lawọn alawọ funfun ti jẹ gaba le awọn alawọ dudu lori ni South Afrika ṣaaju ija ominira Nelson Mandela.

Lọwọ yii, ida 72% oko ilẹ naa lo wa lọwọ awọn alawọ funfun gẹgẹ bii atẹjade ijọba lọdun 2017 amọ o jẹ iyalẹnu pe ida 7.3% pere ni awọn alawọ funfun orileede ọhun.

Awọn alawọ funfun ti wọn jẹ agbẹ lo ni dukia to pọ ju ẹnikẹni lọ nibẹ, amọ gbogbo ẹya ni awọn ẹni ibi n kọlu ninu oko wọn.

Awọn alagbara n sọ pe awọn agbẹ alawọ funfun nikan ni awọn ẹni ibi n kọlu, amọ ohun to han gbangba ni pe gbogbo ẹya lo n koju eto abo to mẹhe ni South Afrika.

Nthabiseng Nthathakana wọ aṣọ funfun niwaju ile kan
Àkọlé àwòrán, Nthabiseng Nthathakana padanu ọkọ rẹ nigba ti awọn ẹni kọlu ṣọọbu wọn

Niluu Meqheleng ti ko jina si Ficksburh ti wọn fi agidi le awọn alawọ dudu si lọpọ ọdun sẹyin, Nthabiseng Nthathakana ni ṣọọbu kan sibẹ.

Laarin oṣu Kinni ọdun yiii, wọn ja wọn lole lasiko ti ọkọ rẹ Thembani Ncgango n ti ṣọọbu ọhun ni irọlẹ.

Oun funra rẹ salọ sile ara adugbo wọn kan nigba ti awọn adigunajale naa dunkoko pe awọn yoo pa wọn ti wọn ko ba ṣilẹkun.

Lẹyinorẹyin, oku Thembani ni Nthabiseng ba nilẹ iwaju ṣọọbu naa.

O ni "wọn gun ṣakaṣaka, bẹẹ ni wọn tun yin in ni ibọn. Okuta ni wọn fi gun."

Ọlọpaa ko tii mu ẹnikẹni fun iwa ọdaran naa titi di oni yii.

Lọwọ yii, Nthabiseng nikan lo n da tọ ọmọ mẹrin ti wọn bi.

O ni gbogbo igba lawọn ọmọ naa maa n bere ẹni to pa baba awọn lọwọ oun.

Ni ti Marthinus, ijọba Amẹrika ti ni ki wọn maa bọ gẹgẹ bi atipo.

O ni oun gbagbọ pe awọn kan fẹ pa ẹya alawọ funfun rẹ ni South Afrika.

Isa-Lee Jacobson ati Tamasin Ford fi kun iroyin yii.