Àwọn ipa tí ìgbésẹ̀ mímú ológun mọ̀kànlá sáhàámọ́, gbẹ́sẹ́ lé bàálù le è ní bí Nàíjíríà ṣe fèsì lórí ìdí tí bàálù rẹ̀ fi balẹ̀ lójijì ní agbègbè Sahel

Awọn asaaju ijọba ologun ni orilẹede Burkina Faso, Niger ati Mali, awọn mẹtẹẹta wọ asọ ologun.

Oríṣun àwòrán, Collage

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Nibayii, awọn alasẹ Naijiria ti sọrọ lori bi baalu Ologun C130 se balẹ si orilẹede Burkina Faso lai gba asẹ.

Atẹjade kan ti ileesẹ Ologun ofurufu Naijiria fisita lori isẹlẹ naa salaye pe baalu naa, to n ko eroja lọ silẹ Portugal, lo sadede ya bara, to si balẹ ni ojiji silẹ Burkina Faso.

Atẹjade naa ni baalu ọhun lo gbera nilu Eko amọ to ni isoro diẹ eyi to mu ko sadede balẹ silu Bobo-Dioulasso lorilẹede Burkina Faso.

O ni papakọ ofurufu to sunmọ ni baalu ọhun balẹ si ni ibamu pẹlu ilana ofin aabo loju ofurufu ati igbesẹ irinajo ofurufu.

"Ikọ Ologun ofurufu wa w ani Alafia, ti awọn alasẹ orilẹede to gba wọn lalejo si n se itọju wọn daadaa.

Ileesẹ Ologun ofurufu Naijiria si mọ riri atilẹyin to ri gba lasiko yii, to si n fi dawọn araalu loju pe a n sisẹ wa nibamu pẹlu ofin ati ilana to de isẹ naa."

Ipa ti isẹlẹ baalu Naijiria to balẹ lojiji nilẹ Burkina Faso le ni lori awọn orilẹede ti ọrọ kan

Amọ o dabi ẹni pe ohun ti ileesẹ Ologun ofurufu Naijiria sọ yii tako iha ti ijọba Ologun nilẹ Burkina Faso kọ si isẹlẹ naa.

Ki isẹlẹ baalu to balẹ lai gba asẹ naa to waye nilẹ Naijiria ti lọ pa ina ete iditẹ gbajọba nilẹ Benin, eyi to n fa awuyewuye lọwọ lagbegbe naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi Ologun ofurufu Naijiria tiẹ di ẹbi isẹlu baalu to balẹ lojiji naa ru isoro ranpẹ ti baalu Ologun naa ni, sibẹ, awọn orilẹede to wa lagbegbe Sahel ni igbesẹ naa fara pẹ titẹ ẹtọ orilẹede Burkina Faso loju, gẹgẹ bii orilẹede olominira.

Bakan naa, bi wọn se gbẹsẹ le baalu Ologun ilẹ Naijiria, ti wọn si mu Ologun mọkanla si ahamọ nilẹ Burkina Faso se afihan pe awọn orilẹede to w ani agbegbe Sahel ti gba akoso oju ofurufu wọn.

Amọ bi wọn ko ba sọra, bawọn orilẹede mẹtẹẹta to wa ni agbegbe Sahel naa se kede pe oun yoo maa gbena woju baalu ki baalu to ba wọ oju ofurufu wọn lai gba asẹ, le di ogun ati iporogan to ba ya.

Yatọ si eyi, igbesẹ naa, isẹlẹ yii ba ajọsepọ to wa laarin orilẹede Naijiria atawọn orilẹede mẹtẹẹta to w ani agbegbe Sahel, to jẹ alamuleti wọn jẹ.

Bakan naa lo le se akoba fun aabo oju ofurufu laarin awọn orilẹede naa, to si le se akoba fun igbogun ti iwa igbesunmọmi to n lọ lọwọ.

Ipa ti isẹlẹ naa le ni lori awọn orilẹede mẹtẹẹta to w ani agbegbe Sahel

Fun awọn orilẹede mẹtẹẹta to wa ni agbegbe Sahel, eyiun Burkina Faso, Niger ati Mali, igbesẹ ibinu ti wọn gbe lati gbẹsẹ le baalu Naijiria, ki wọn si tun ko ọmọ ogun mọkanla si ahamọ ni itumọ nla.

Igbesẹ naa si n se afihan pe wọn ko ni faramọ lilọ bibọ tabi yiyọkẹlẹ Ologun lati awọn orilẹede miran lai gba asẹ ni oju ofurufu wọn lai naani awijare ti iru orilẹede bẹẹ ni.

Ipa ti isẹlẹ naa le ni lori awọn orilẹede mẹtẹẹta to wa ni agbegbe Sahel

Fun awọn orilẹede mẹtẹẹta to wa ni agbegbe Sahel, eyiun Burkina Faso, Niger ati Mali, igbesẹ ibinu ti wọn gbe lati gbẹsẹ le baalu Naijiria, ki wọn si tun ko ọmọ ogun mọkanla si ahamọ ni itumọ nla.

Igbesẹ naa si n se afihan pe wọn ko ni faramọ lilọ bibọ tabi yiyọkẹlẹ Ologun lati awọn orilẹede miran lai gba asẹ ni oju ofurufu wọn lai naani awijare ti iru orilẹede bẹẹ ni.

Baalu ologun nla kan, to jẹ alawọ ewe, n fo loju ọrun, awakọ baalu to wọ asọ ologun tii se alawọ ewe wa ninu rẹ.

Oríṣun àwòrán, @Defence Headquaters

Àlàyé rèé lórí ìdí tí Burkina Faso ṣe mú ológun Nàíjíríà mọ́kànlá sí àhámọ́, gbẹ́sẹ̀ lé bàálù iléeṣẹ́ ológun

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe orilẹede Burkina Faso ti mu awọn omo ogun mọkanla ti wọn jẹ ọmọ Naijiria, to si tun gbẹsẹle baalu wọn.

Lasiko ti awọn Ologun naa duro lojiji nilu Bobo-Dioulasso, tii se ilu to tobi sikeji nilẹ Burkina Faso, ni wọn gbe igbesẹ naa.

Ana ọjọ Aje, ọjọ Kẹjọ osu Kejila ni isẹlẹ naa waye.

Baalu Ologun to jẹ ti Naijiria naa, C130, lo gbe ọmọ ogun mẹsan ati osisẹ baalu meji.

Orilẹede Mali, Niger ati Burkina Faso to wa ni agbegbe Sahel bu ẹnu atẹ lu bi baalu ologun Naijiria se balẹ si Burkina Faso lai gba asẹ

Wayi o, apapọ awọn orilẹede to wa ni agbegbe Sahel, eyiun orilẹede Mali, Niger ati Burkina Faso ti wa fi atẹjade kan sita lati bu ẹnu atẹ lu isẹlẹ naa.

Awọn orilẹede Sahel naa wa fi ewe ọmọ mọ orilẹede Naijiria leti pe ko dẹkun rinrin lagbegbe awọn lai gba asẹ, bibẹẹ kọ, awọn yoo gbena woju rẹ .

Awọn orilẹede naa ni awọn ti n daabo bo oju ofurufu awọn pẹlu ọwọ agbara to ga nitori isẹlẹ naa.

"Aabo awọn agbegbe oju ofurufu wa ti wa digbi, a si ti pasẹ pa kawọn Ologun ofurufu wa gbe igbesẹ nla lori baalu ki baalu to ba tako asẹ wa ati ikilọ yii."

Minisita feto akoso agbegbe nilẹ Burkina Faso, Emile Zero, si lo sọrọ lorukọ awọn orilẹede Sahel naa lori mohunmaworan orilẹede naa.

Emile salaye pe baalu Ologun Naijiria naa lo balẹ si orilẹede Burkina Faso lai gba asẹ, ti awọn si ti bẹrẹ iwadi lori isẹlẹ naa.

Isẹlẹ yii lo waye lẹyin ti orilẹede Naijiria fidi rẹ mulẹ pe oun ti fi baalu Ologun ransẹ lati lọ pa ina iditẹgbajọba to waye nilẹ olominira Benin lọjọ Aiku.

Bẹẹ ba gbagbe, awọn orilẹede to w ani agbegbe Sahel yii lo ti kede saaju pe awọn ko fẹ ni ajọsepọ kankan mọ pẹlu ajọ ECOWAS.

O si seese ko jẹ pe o n mu aabo agbegbe rẹ lọkunkundun ni nitori bi ilẹ Naijiria se dunkooko lasiko tawọn Ologun gba akoso ilẹ Niger.

Awọn orilẹede mẹtẹẹta to w ani agbegbe sahel naa, eyiun Burkina Faso, Mali, ati Niger lo wa labẹ isejọba Ologun, ti wọn si n kerora nipa aabo to mẹhẹ tori ikọlu awọn agbesunmọmi.