Kàyééfì! Oyin ta akẹ́kọ̀ọ́ méjì pa ní Ghana

Awọn oyin ṣuru jọ soju kan naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Inu ọfọ ni awọn mọlẹbi meji kan ti oyin ta awọn ọmọ wọn pa nileẹkọ lorilẹede Ghana wa bayii latari iku awọn ọmọ naa.

Ọjọru ọsẹ yii ni wahala naa waye nile ẹkọ Evangelical Presbyterian Basic School to wa lagbegbe Anloga, ẹkun Guusu-Ila-Oorun orilẹede Ghana.

Olukọ agba nile ẹkọ naa, Thywill Deynu, ṣalaye pe ọjọ ori awọn ọmọ to di oloogbe naa ko ti i to ọdun mẹwaa

O ni awọn akẹkọọ ẹka jẹle-o-sinmi ti wọn ko le sare to bẹẹ ni awọn oyin naa kọju ija si ju.

Yatọ si awọn ọmọde meji to ba ikọlu oyin naa rin, awọn miran tun farapa bo ṣe sọ.

Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?

Gẹgẹ bi alaye Olukọ agba, Thywill Deynu, o ni lasiko ti awọn akẹkọọ naa n gbaradi lati lọ fun isinmi opin saa ni wahala ọhun waye.

Deynu sọ pe ere bọọlu kan ni awọn akẹkọọ n kopa ninu rẹ lọwọ ki wọn to maa ju oko lu awọn oyin naa nibi ti wọn ta afárá wọn si.

Eyi lo ni o fa a ti awọn oyin fi ṣí kuro ni aaye wọn, ti wọn si bẹrẹ si i ta awọn akẹkọọ to tọ́ wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Olukọ agba ṣalaye pe:

"Awọn akẹkọọ jẹle-o-sinmi ni awọn oyin yẹn dojukọ ju , nitori wọn ko le gba ara wọn kalẹ."

Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ eto ilera lati ileewosan ijọba Keta Municipal, fidi ẹ mulẹ pe akẹkọọ mẹrin ni wọn sare gbe de ọdọ awọn fun itọju, ṣugbọn meji ninu wọn jade laye.

"A yẹ awọn ti won sare gbe lọ si yara itọju pajawiri wo, a si ri I pe meji ninu wọn lo wa nipo to lewu."

Dokita Fiifi Agyemang, lati ileewosan naa lo sọ bẹẹ.

O ni ọkan ninu wọn ti pada kuro nipo ewu naa, awọn si ti yọnda akẹkọọ miran l'Ọjọbọ, nigba ti ifarapa tiẹ naa ko pọ.

Mi o ri iru ibanujẹ bayii ri, bawo ni mo ṣe fẹ bọ ninu eyi-Iya ọkan lara awọn ọmọ to kú

Nigba to n ṣalaye ibanujẹ to gbe e wọ bayii bi ẹwu latari iku ọmọ rẹ, iya ọkan lara awọn ọmọ to ku naa, Mawuko Kumeko (ọmọ ọdun mẹrin) sọ pe adanwo naa kọja agbara oun.

O ni bo ṣe n jọ oun loju pe ọmọ ti nnkan ko ṣe, lo ṣe bẹẹ di oloogbe, bẹẹ naa ni ọkan oun ṣe n poruru.

"Mi o ti i ri iru ibanujẹ yii ri laye mi,bawo ni mo ṣe fẹ bọ ninu eyi?"

"Mo mu ọmọ mi lọ sile ẹkọ, mo si kọri sọna ọja pẹlu awọn aburo rẹ, afi bi mo ṣe de ti mo gbọ pe oyin ta ọmọ mi."

Bẹẹ ni iya naa wi.

Ni ti mọlẹbi keji to padanu ọmọ, ọmọ obinrin ni awọn padanu, o si jẹ ọmọ ọdun mẹsan-an.

"Ohun to le fa iku kia ni ki oyin ta eeyan pa''

Ki oyin ta eeyan pa maa n waye pẹlu ohun ti awọn dokita n pe ni anaphylaxis, paapaa awọn ti oro naa ba ṣe ajeji lara wọn.

Dokita kan, Andrews Baha lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.

O ṣalaye pe:

"Ohun ti a n pe ni anaphylaxis lo maa n jẹ ko ṣoro fun ẹni ti oyin ba ta lati le mi daadaa, nitori ọna to n gba mi yoo ti dí, gẹgẹ bo ṣe maa n ṣe awon to ba ni ikọ seemi-seemi ti a mọ si asthma.

"O le fa ki ara maa gbọ̀n tabi ki ọkan daṣẹ silẹ."

Dokita Baha ṣalaye pe ohun to le fa ki ẹmi eeyan bọ kia ni bi oyin ba ta eeyan, o gba awọn eeyan ti oyin ba ta nimọran lati tete wa itọju pajawiri kia.

Iṣẹlẹ oyin to n ta awọn eeyan yii ni ẹlẹẹkẹta iru rẹ to waye laaarin ọsẹ kan kaakiri Ghana.

Lọjọ kẹtala oṣu Kejila yii, oyin ta agbẹ kan pa ni ẹkun Guusu -Ila-Oorun Ghana kan naa, agbegbe Akatsi, ni apa Ariwa gan-an lo ti waye.

Bakan naa ni iya agba ẹni ọdun mejilelọgọrin (82) kan naa lugbadi oyin gẹgẹ bi ẹka iroyin Ghana News Agency ṣe sọ.

Bẹẹ naa ni olori agbegbe kan naa lugbadi oyin lọjọ kerinla oṣu Kejila yii, ni Ariwa Ghana (Kpandai) lasiko to fori ja ile wọn nigba to n lọ si agbegbe miran.

Ajọ panapana ilẹ naa ti wa gba awọn eeyan nimọran, lati kan si wọn bi oyin ba gba agbegbe kan.

Wọn kilọ pe kawọn eeyan yee wa ija awọn oyin pẹlu.

Agbẹnusọ ileeṣẹ panapana lẹkun Ashanti, Daniel Antwi Boasiako, kilọ pe kawọn eeyan yee lo nnkan ikunra oloorun didun nibi ti awọn oyin ba wa.

Ki wọn ma si ṣe tọ́ oyin tabi mu wọn ṣere.

"Ẹ kuro nibi ti ẹ ba ti ri oyin kan tabi meji, eyi le jẹ apẹẹrẹ pe wọn fẹ kọlu yin.

"Bi ẹ ba si ri ẹranko kan ti oyin n doju ija kọ lọwọ, ẹ ma ṣe gbiyanju lati gba a kalẹ, afi to ba jẹ ẹ wọṣọ idaabobo lọwọ oyin nikan ."

Bẹẹ ni agbẹnusọ ajọ panapana naa kilọ.