Aworan Afrika to rẹwa ju laarin ọsẹ

Ẹsa ninu awọn aworan to rẹwa ju lati Afrika ati tawọn ọmọ Afrika lagbaye ninu ọsẹ yii.

Awọn onijo n gba ẹrọ isọ kọja

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ni orilẹede Kenya, awọn onijo n gba ẹrọ isọ kọja ki wọn to wọ papa ọkọ ofurufuu Jomo Kenyatta lati ki ife ẹyẹ bọọlu agbaye kaabọ sorilẹede naa.
Awọn onijo nigboro Johannesburg, lorilẹede South Africa lọjọ kẹrinlelogun, Osu-keji, ọdun 2018

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Awọn onijo si tun da awọn eeyan lara ya nigboro Johannesburg, lorilẹede South Africa, nibi ti wọn ti n ṣẹ ajọdun ọdun tuntun ounka-ọjọ China
Awọn onijo maa n jo lati fibukun si gbogbo ile-ikẹrusi nigba ajọdun ọdun tuntun ilẹ China Johannesburg, lorilẹede South Africa ọjọ kẹrinlelogun, Osu-keji, ọdun 2018

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Wọn si tun s'afihan ijo ibilẹ ẹkun nigba t'awọn eeyan dunnu amojubaa Ọdun Aja
Arabirin orilẹede Kongo kan joko silẹ ni waju ibudo awọn atipọ kan lọjọ kẹ̀tadinlogbọn, Osu-keji ọdun 2018 ni Bunia

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ni orilẹede DRC, nibi ti ogun ti sọ awọn eeyan di atipọ, obirin alasala kan joko.
Obirin Fulani kan n tun idiri rẹ ṣẹ lori poponaa Dapchi, nipinlẹ Yobe, ni Naijiria lọjọ kẹtadinlọgbọ Osu-Keji, ọdun 2017

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Oni fọto yii s'akiyesi awọn awọ alarambara ni abule Dapchi, ilu kan to n ṣe eema ijinigbe awọn akẹkọbirin.
Alufaa onigbagbọọ orilẹede Ethiopian kan n gbadura lẹgbẹ ilẹkun ile-ijọsin Church of the Holy Sepulchre nigboro Jerunsalẹẹmu lọjọ kẹrindinlọgbọn Osu keji ọdun 2018

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ni Jerusalẹẹmu, alufaa onigbagbọọ orilẹede Ethiopia kan n gbadura lẹgbẹ ilẹkun ile-ijọsin Holy Sepulchre to wa ni titi.
Awọn eeyan n yoju lati ferese ọkọ akero ni waju paali ipolongo idibo aarẹ Ijibiti Abdel Fattah al-Sisi fun ibo aarẹ ti n bọ yii ni Cairo, orilẹede Ijibiti lọjọ kejidinlọgbọ Osu-keji, ọdun 2018

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Lẹyin odi ilu naa ni orilẹede Ijibiti, orilẹede naa n mura ati dibo, gẹgẹ bi awọn aworan yii ṣe fi han ni oluilu orilẹede naa, Cairo.
Annastacia Wainaina, ẹni ọdun 34, jẹ ọkan lara awọn ti wọn wa ọkọ akero "matatu" kan

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọkọ akero miiran niyi, sugbọn lakoko yi nigboro Nairobi, lorilẹede Kenya ni nibi ti Annastacia Wainaina, ẹni ọdun 34, ti jẹ ọkan lara awọn awakọ to n ṣiṣẹ ninu ọkọ akero "matatu" kan - to jẹ tijọba ati ti aladanikan ni.
Ifrah Ahmed (lapa alafia) pẹlu Aja Naomi King to ṣẹ bi rẹ ninu fiimu kan ti wọn safihan rẹ ile itura Westin Hotel nigboro Dublin

Oríṣun àwòrán, PA

Àkọlé àwòrán, Loke okun ni igboro Dublin, orilẹede Ireland, ni ọmọ Somalia to jẹ ajafẹtọ Ifrah Ahmed (lapa alafia) ti duro ya foto pẹlu Aja Naomi King, to n kopa ninu fiimu kan gẹgẹ bi ajafẹtọ naa nipa ipolongo rẹ lori didẹkun didabẹ fun obirin.
Awọn ọmọ ikọ agbabọọlu obirin Ghana wọn dunnu pẹlu ife ẹyẹ lẹyin igba ti wọn bori ojugba wọn ti ilẹ Ivory Coast lọjọ kẹrinlelogun Osu-keji, ọdun 2018

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Nipari, ẹrin lawọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu obirin orilẹede Ghana bu si l'Abidjan lẹyin igba ti wọn ṣẹgun olugbalejo wọn, ẹgbẹ agbabọọlu Ivory Coast, lati gba ife ẹyẹ awọn obirin Iwọ-oorun Afrika - West African Football Union (UFOA) zone B women's tournament.

Awọn awroan yii wa lati ọwọ: AFP, Reuters, PA and Getty Images