Death Sentence: Ọmọ ọdún 21 gba ìdájọ́ ikú nítorí ó jalè ni sọ́ọ̀bù oògùn

Oríṣun àwòrán, Justice
Ọmọ ọdun mọkanlelogun, Ekemini Edet ti gba idajọ iku nile ẹjọ giga kan ni ìpínlẹ Uyo
Adajọ agba, Okon Okon naa gbe idajọ naa kalẹ pe ọmọ ohun ja ile oogun MI AMAN lole.
Iroyin sọ pe ọmọ naa jẹwọ pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an pe o jale ni ile itaja oogun naa.
Ile itaja naa wa ni opopona Aka Nung Udoe ni Uyo ninu osu kẹta odun to kọja .
Ninu idajọ rẹ Okon Okon so pe ọmọ naa jẹbi ẹsun idigunjale naa.
Adajo ni eyi si jẹ pe iku ni ere rẹ labẹ ofin ipele ikini ẹsẹ (2a) eyi ti o sọ nipa idigunjale ati gbígbe ohun ija labẹ ofin ìjọba apapọ ọdun 2004
O ni adajọ ti se "ohun to tọ lati jè ki olujẹjọ mọ pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an"
"Nitori idi eyi mo ri e olujẹjọ yii jẹbi esun ti a si ṣe idajọ re.
Idajọ ile ẹjọ ni pe iwọ Ekemini Edet ki wọn lọ fi ọrun rẹ kọgi titi ti ẹmi yoo fi bọ lọrun rẹ@














