Nigeria diplomat manhandled in Indonesia: Orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti sọ àwọn ìgbésẹ̀ tó fẹ́ gbé lórí aṣojú ìjọba Nàìjíríà tí wọ́n kọlù ní Jakarta

Minista fọrọ ilẹ Okeere ni Naijiria , Geoffery Onyeama

Oríṣun àwòrán, Ministry of foreign affairs Nigeria

Ijọba Naijiria ti ranṣẹ pe aṣoju rẹ ni Indonesia wale fun ijiroro lori bi awọn oṣiṣẹ wọlewọde orilẹede naa kan ṣe fun oṣiṣẹ ileeṣẹ aṣoju ijọba Naijiria lọrun mọ inu ọkọ

Minista fọrọ ilẹ Okeere ni Naijiria , Geoffery Onyeama ni awọn yoo gbe ajọṣepọ pẹlu Indonesia yẹwo lori ọrọ naa nitoripe ohun to ku diẹ kaa to ni.

Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu awọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun nilu Abuja, Minisita fọrọ ilẹ okeere Geoffery Onyeama ṣalaye pe ijsba orilẹede Naijiria ko ni fi aye gba orilẹede yoowu lagbaye lati hu iwa kotọ fun ọmọ Naijiria yoowu.

O ni alaye ti aṣoju ijọba orilẹede Indonesia ṣe fun ijsba Naijiria tubọ mu ki ero ijọba Naijiria mulẹ sii pe ko yẹ ki irufẹ ihuwasi bẹẹ waye si ọmọ Naijiria yala oṣiṣẹ ileeṣẹ aṣoju ijọba tabi mọ Naijiria kankan.

atẹjade ti ileeṣẹ ọrọ ilẹ Okeere ni Naijiria fi sita

Oríṣun àwòrán, Ministry of foreign affairs nigeria

Fidio kan to gbaye kan ṣe afihan bi awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ wọlewọde ilẹ Indonesia ṣe hu iwa aitọ si oṣiṣẹ ileeṣẹ aṣoju ijsba Naijiria kan nibẹ.

Minisita fọrọ ilẹ okeere naa ni, bi o tilẹ jẹ pe ijọba orilẹede Indonesia ti tọrọ aforiji lori iwa kotọ naa, orilẹede Naijiria n fẹ ki wọn gbe igbesẹ ibawi to yẹ lori awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ wọlewọde naa.

Iroyin sọ pe oṣiṣẹ ileeṣẹ aṣoju ijọba Naijirian naa n lọ ra ọja nile itaja nla kan ni ilu Jakarta, tii ṣe olu ilu orilẹede naa.