Rochas Okorocha : Wo ìdí tí ìlú Iselu kò ṣe fi Rochas Okorocha joyè mọ́

Rochas Okorocha

Oríṣun àwòrán, Rochas okorocha

Oye to yẹ ko bọ si ọwọ Senetọ Rochas Okorocha, ni ilu kan nipinlẹ Ogun, ti bọ mọ lọwọ.

Ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2021,ni ilu Iselu nipinlẹ Ogun kọ lẹta si Okorocha, to tun ti jẹ gomina ipinlẹ Imo ri pe, àwọn fẹ ẹ fi jẹ oye.

Sugbọn ni ṣe ni ọba ilu naa, Oba Ebenezer Akintunde Akinyemi, Eselu ti Òṣèlú, tún kọ lẹta miran si Senetọ Okorocha lọjọ pe awọn ko fi jẹ òye mọ, ati pe ayẹyẹ iwuye ko ni i waye mọ.

Ifinijoye naa ni i ba sọ Okorocha di Ọtunba Asọludẹrọ ti ilu Iselu, nijọba ibilẹ Yewa, nipinlẹ Ogun.

Ọba Akinyemi sọ pe igbesẹ oun waye nitori ki alaafia ati isọkan le wa.

Iwe ti ọba Eselu kọ

Oríṣun àwòrán, Eselu ti ilu iselu

Botilẹjẹ pe ko sọ nkan pato to mu ko yi eero rẹ padà, Ọba Akinyemi sọ ninu lẹta tuntun naa pe kii ṣe pe awọn korira Okorocha.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021, lo yẹ ki iwuye naa o waye.

Titi di akoko ti a gbe iroyin yii jáde, Senetọ Okorocha ko ti i sọ ohunkóhun lori igbesẹ Eselu.

Ki lo le faa ti wọn le fi fa ọwọ ewe oye pada lọdọ eniyan kan

Rochas okorocha nbọwọ pẹlu ọbalaye kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Idi ti wọn ko fi fi Senetọ Rochas Okorocha joye mọ ko han siwa, sugbọn ninu ọrọ to ba BBC sọ, Araba ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon sọ pe igbesẹ naa ko jẹ tuntun.

O ni wọn le má fi eniyan joye mọ, wọn si tun le rọ eniyan loye, nitori iroyin ìwà buburu.

O sọ pe o ṣe e ṣe ki wọn o ti gbọ́ iroyin ti ko dara nipa Okorocha lo mu wọn ṣe bẹ ẹ.