Algeria: Ààrẹ Abdelaziz Bouteflika re 'bi àgbà ń rè

Abdelaziz Bouteflika

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Abdelaziz Bouteflika
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Abdelaziz Bouteflika fẹrẹẹ lo ogun ọdun ninu aginju oṣelu ki wọn to dibo yan an gẹg bi Aarẹ orilẹede Algeria lọdun 1999.

Ipa ti o ko ninu ija fun ominira Ageria fun un ni iyi nla lagbaye bi o tilẹ jẹ wi pe ero tirẹ ati aato maa n tako ohun ti awọn alawọ funfun n fẹ.

Kii ṣe bii tawọn adari mii lẹkun naa, isejọba tirẹ ggẹ bi aarẹ bori ifẹhonu han awọn ara Arab lodi si ijọba.

Wọn bi Abdelaziz Bouteflika ni Morocco ni ọjọ keji oṣu kẹta ọdun 1937; ara orilẹede Algeria lawọn obi rẹ.

Ọpọlọpọ igbe aye rẹ lo gbe ni Algeria ti o si dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu National Liberation Front (FLN) nigba to wa ni ọdọ langba.

Lẹyin ominira lọdun 1962, Aarẹ Ahmed Ben Bella fi Bouteflika jẹ minisita fun ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya. Lọdun to tẹle e, o di minisita fun ọrọ ilẹ okere.

Saddam Hussein ati Hafez al-Assad pẹlu Bouteflika

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Bouteflika, ẹni ikeji lati apa ọtun pade Saddam Hussein

Ṣugbọn nigba to maa fi di ọdun 1965, ẹgbẹ oṣelu FLN ti wa ninu idamu. gba gba lo yiyọ Ben Bella loye ti wọn fi Houari Boumedienne sibẹ.

Ṣugbọn awọn alatako rẹ pada fẹsun kan an pe o lọwọ ninu iku ọmọ gb oṣelu FLN marun un.

Ọpọ lo ri i gẹgẹ bi opomulero iṣejọba, Bouteflika ni agbatẹru bi Algeria ṣe goke ninu ẹgbẹ to n jẹ Non-Aligned Movement.

Pẹlu iku Boumedienne ni 1978, orisun agara Bouteflika tan. O ti ro pe oun yoo di aarẹ lẹyin Boumedienne ṣugbọn awọn ẹgbẹ kan laarin awọn ologun yan Chadli Bendjedid dipo rẹ.

Ati adun ati ipenija oṣelu ni Bouteflika yago fun lẹyin gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an nigba to n dari ile iṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okere lo ba na papa bora kuro ni Algeria ldun 1983 ti ibi to wa si ru ni loju.

Àwọn ọmọ ogun Algeria loju popo lọdun 1990

Oríṣun àwòrán, AP

Àkọlé àwòrán, Wahala mu ki awọn ologun maa ṣọna gbogbo iloro ni gbogbo igba

Ẹgbẹ oṣelu FLN to ti jọba ni orilẹede ẹlẹgb oṣelu kan lati igba ominira rẹ wa pin si ẹgbẹ modernisers ati conservatives; igba yẹn ni Bouteflika to jẹ ti conservative ba pada lati ibi to ṣako lọ.

Bouteflika pada sori itage oṣelu lọdun 1999 nigba to dupo aar plu atilẹyin awọn ologun. O jẹ ọkan lara awọn oludije meje ṣugbọn ṣe lawọn mẹfa to ku ni awọn o dupo aarẹ mọ ti wọn si fi ẹhonu han pe wọn ti da ibo ru fun anfani Bouteflika.

Ọpọlọpọ ri i gẹgẹ bi adari to lee yanju aawọ awọn araalu eyi to bẹ silẹ lẹyin ti awn ologun da si i lati dena ki ẹgbẹ ẹlẹsin Islam kan bori ninu idibo gbogbo gbo ti ọdun 1992.

Laarin oṣu marun un pere to gori oye, wọn tẹwọ gboriyin fun un lori aato rẹ fun iyanju aawọ eyi to fun ọpọlọpọ ẹgbẹ Islam.

Awọn Kasbah ni Algiers

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọpọ ara Algeria n sọ pe ko ṣe nkankan lati mu ọrọ aje gberu sii

Bakan naa, o ṣe iṣẹ lati dọrẹ pẹlu orilẹede aladugbo wọn, Morocco. Orilẹ̀ede mejeeji ti wa ninu aigbọraẹni ye lori ọjọ iwaju apa Ila Oorun Sahara.

Wọn tun yan Bouteflika gẹgẹ bi aarẹ lọdun 2004 ti o si fi ẹyin oludije marun un janlẹ lati gba ibo to pọ ju.

Awọn alatako rẹ fi ẹsun ole ibo kan an bi o tilẹ jẹ pe ko ni aridaju awọn onwoye lati ilẹ okere to mojuto idibo naa.

Ọpọlọpọ ara Algeria lo kan sara si i pe o da alafia pada si orilẹede naa wọn si ro o wi pe o nilo saa kan sii ni ijọba.

Ni ọdun 2008, o ri aridaju ayipada ninu ofin Algeria eyi to yọ gbedeke saa meji ti aarẹ le lo, igbesẹ yii si ni ile igbimọ aṣofin wọn ṣe atunṣe rẹ lọdun 2008.

Abdelaziz Bouteflika nibi to ti n dibo

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, O ni oun ko lọwọ ninu ẹsun iwa ole ninu ibo

Lọdun to tẹle e, Bouteflika gbe apoti ibo fun saa kẹta o si ni ida aadọrun ninu ọgọrun ibo eyi si tun mu ki ẹgbẹ oṣelu alatako tun ri wi nipa iwa ole idibo.

Gbogbo igba lo maa n doju kọ ifẹhonu han lasiko to wa lori alefa ṣugbọn nigba to ku diẹ ki oṣu kejila ọdun 2010 pari, atako nla yọju si aato rẹ ti awọn afhonu han si tu sigboro lati fi ibinu wọn han si ọrọ ọbayejẹ, ọwọngogo ounjẹ ati airilegbe.

Fifi ẹhonu han yi di rangbọndọn kete ni osu ti owo ounjẹ wẹwẹwẹ goke sii ti wọn si fipa mu ki ijọba din i ku.

Lọjọ kẹẹẹdogun oṣu kẹrin, Bouteflika fara han lori ẹrọ mohunmaworan to ti n ṣeleri lati ṣatunṣe iwe ofin ati itẹsiwaju ijọba awa ara wa ni Algeria.

Abdelaziz Bouteflika

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Wọn fi ẹsun kan an pe o n tẹ awọn alatako ri mọlẹ lati ṣi wa lori alefa

Abdelaziz gbiyanju lati rii pe alafia jọba ni orilẹede Algeria bi o tilẹ jẹ pe awọn onija ẹsin Islam ṣi tẹsiwaju ti wọn si yan orukọ tuntun Al-Qaeda lọdun 2007, wọn n ṣe ikọlu kaakiri awọn orilẹede agbegbe.

Bakan naa Bouteflika ko ribi koju awọn ẹsun iwa ajẹbanu ti wọn fi kan an eyi to tapo si aṣọ ala rẹ pupọ lori alefa.

Wọn wa ri aato atunṣe rẹ bi eyi ti ko to nkan to si pẹ, awọn ara Algeria paapaa ọdọ ko wa ni suuru mọ pẹlu ohun ti wọn ri gẹgẹ bii ipinu rẹ lati lo ilana to lodi si ijọba awa ara wa lati tẹ ẹ pa sori alefa gẹgẹ bi aarẹ lai kuro nibẹ mọ.