Osun Election 2018 : Ilé ẹjọ́ ní Adeleke kò lẹ́tọ̀ọ́ láti díje dupò gomina

Aworan Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/Facebook

Àkọlé àwòrán, Adeleke ni oludije ẹgbẹ òṣèlú PDP nínú ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun

Ile ẹjọ giga to wa ni ilu Abuja ti fagile iyansipo Ademola Adeleke gẹgẹ bi oludije sipo gomina ni ẹgbẹ oselu PDP ninu idibo gomina to waye ninú Osu Kẹsan, ọdun 2018 ni ipinlẹ Osun.

Ademola Adeleke to n soju ẹkun idibo Iwọ-Oorun ipinlẹ Osun ni Ile Igbimọ Asofin lo dije dupo gomina ni ọdun to kọja.

Wahab Raheem ati Adam Habeeb ti ẹgbẹ oselu APC lo gbe Ademọla Adeleke lọ si ile ẹjo wi pe ko ni ju sabuke ile ẹkọ girama, eleyii ti yoo fun ni anfaani lati dije.

Àkọlé fídíò, Okùnrin SARS náà sọ pé òun máa pa èèyàn síbi ni- Aladugbo

Lasiko to n da ẹjọ naa, Adajọ Agba Oathman Musa sọ wi pe iwadii fihan pe ọdun 1976 ni Adeleke wọ ile iwe girama, amọ ti ko si iwe ẹri to fihan pe o jade iwe mẹwa ni ọdun 1980.

Amọ, agbẹjọrọ to n soju Adeleke Nathaniel Oke bu ẹnu atẹ lu idajọ naa nitori adajọ naa tọ ọna ti ko ba ofin mu, ti o si da iwe ẹri WAEC to fihan pe Adeleke ni iwe ẹri WAEC rẹ.

Àkọlé fídíò, Ojojúmọ ní mọ ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ọmọ mi to jẹ akanda

Ti a ko ba gbagbe, ajọ to n risi idanwo asekagba ile ẹkọ girama, WAEC fi lede lasiko idajọ wi pe lootọ ni Adeleke se idanwo WAEC ni Osu Karun/Kẹfa, ọdun 1981.