Osun governorship election: PDP àti APC fàdúrà jagun ṣáàjú ìdàjọ́ ìgbìmọ̀ tó n gbẹ́jọ́ ìdìbò Ọṣun

Oyetọla ati Adeleke

Oríṣun àwòrán, facebook

Diẹ lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ati Peoples Democratic Party (PDP), ti n ṣe eto aawẹ ati adura lati le ri ojurere gba lọdọ igbimọ to n gbọ ẹsun to jẹyọ lẹyin idibo gomina to waye nipinlẹ Ọṣun lọdun 2018.

Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Ademọla Adeleke lo pe ẹjọ niwaju igbimọ naa lati fi tako esi ibo ti ajọ INEC kede pe oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Gboyega Oyetọla, lo jawe olubori ninu idibo naa.

Àkọlé fídíò, Adeleke fọhùn, 'èmi ni gómìnà tí wọ́n dìbò yàn'

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, agbẹnusọ fun oludije ẹgbẹ PDP, Ọgbẹni Rasheed ṣalaye wi pe awọn ti gba aawẹ ọlọjọ mẹta ati meje 'lati fi wa ojurere Ọlọrun' lẹyin ti awọn ti ṣe gbogbo nkan to yẹ gẹgẹ bi eniyan.

Eto adura

Oríṣun àwòrán, Rasheed Adeleke

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ẹgbẹ ati awọn olori ẹgbẹ lo korajọ pọ silu Ẹdẹ, ti i ṣe ilu abinibi Ademọla Adeleke fun eto adura naa.

O ni awọn ọmọ ẹgbẹ ati awọn olori ẹgbẹ lo korajọ pọ silu Ẹdẹ, ti i ṣe ilu abinibi Ademọla Adeleke fun eto adura naa.

Bakan naa ni ọkan lara awọn to ṣeto adura naa fun ẹgbẹ APC, Comrade Sikiru Tijani sọ fun BBC pe awọn gbagbọ pe adura to gba ẹtọ awọn fun wọn pada lọdun 2007 yoo tun ran awọn lọwọ lori ẹjọ ti Adeleke pe.

O ṣalaye pe awọn ni idaniloju to peye ninu esi ibo to gbe ẹgbẹ APC wọle, ṣugbọn awọn ko gbọdọ ma gba adura si Ọlọrun.

Ati Ademọla Adeleke ati Gboyega Oyetọla gbagbọ pe awọn lo jawe olubori ninu idibo naa.