Sẹ́nétọ̀ Ademọla Adeleke ń jẹ́jọ́ aṣemáṣe lásìkò ìdánwò

Oríṣun àwòrán, @IsiakaAdeleke1
Lẹyin ti awọn ọlọpaa ti gbe e lọ siwaju ile ẹjọ ni ọjọru fun ẹsun iwa aitọ lasiko idanwo, ile ẹjọ giga apapọ kan nilu Abuja ti gba oniduro Sẹnetọ Ademọla Adeleke, oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Awọn ọlọpaa gbe Sẹnetọ Adeleke atawọn mẹrin miran lọ siwaju Onidajọ I.E. Ekwo nibi ti awọn mẹrẹẹrin ti ni awọn ko jẹbi ẹsun mẹrẹẹrin ti wọn fi kan awọn.
Sikiru Adeleke, Alhaji Aregbesola Muftau to jẹ Ọga agba ile ẹkọ girama Ojo-aro Community grammar school, Gbadamosi Ojo to jẹ akọwe agba ileewe naa, pẹlu Dare Samuel Olutọpẹ to jẹ olukọ nibẹ ni wọn pe lẹjọ pe wọn lọwọ ninu iwa aṣemaṣe lasiko idanwo fun aṣekagba ileewe girama NECO June/July 2017.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ni kete ti wọn ti sọ niwaju ileẹjọ naa pe awọn ko jẹbi ẹsun ni adajọ ti gba oniduro awọn mẹta pẹlu Sẹnetọ Adeleke.
Agba agbẹjọrọ, Alex Izinyon SAN, lo n ṣoju fun sẹnetọ Adeleke, nigba ti Nathaniel Oke SAN, ati Abdusalami Abdufatai n gbẹjọro fun awọn olujẹjọ keji ati ikẹta.
Meji ninu awọn ti wọn n jẹjọ naa ni wọn fi pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn nitori aisi nile agbẹjọro wọn lati beere fun gbigba oniduro.
Ile ẹjọ ni oun fun Sẹnetọ Adeleke ni anfani oniduro nitori ipo rẹ lawujọ, amọṣa o gbọdọ fi iwe irinna rẹ soke okun ṣọwọ si akọwe agba ileẹjọ naa, ko si gbọdọ rinrin ajo lọ si oke okun lai gba aṣẹ lọwọ lọdọ ile ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, @IsiakaAdeleke1
Nibayii, ile ẹjọ ti wa sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun, ikejidinlogun ati ikọkandinlogun oṣu kejila.
Awọn ọlọpaa gbe Sẹnetọ Adeleke atawọn mẹrin miran lọ siwaju Onidajọ I.E. Ekwo nibiti awọn mẹrẹẹrin ti ni awọn ko jẹbi ẹsun mẹrẹẹrin ti wọn fi kan awọn.
Sikiru Adeleke, Alhaji Aregbesola Muftau to jẹ Ọga agba ile ẹkọ girama Ojo-aro Community grammar school, Gbadamosi Ojo to jẹ akọwe agba ileewe naa, pẹlu Dare Samuel Olutọpẹ to jẹ olukọ nibẹ ni wọn pe lẹjọ pe wọn lọwọ ninu iwa aṣemaṣe lasiko idanwo fun aṣekagba ileewe girama NECO June/July 2017.
Ni kete ti wọn ti sọ niwaju ileẹjọ naa pe awọn ko jẹbi ẹsun ni adajọ ti gba oniduro awọn mẹta pẹlu Sẹnetọ Adeleke.

Oríṣun àwòrán, @IsiakaAdeleke1
Adeleke yóò jẹ́jọ́ lẹ́yìn ìdìbò Osun - Ọ̀gá ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, @IsiakaAdeleke1
Aarẹ Muhammadu Buhari ti pasẹ fun Ọga Agba Ọlopaa, lati ti ọwọ ọmọ rẹ bọ asọ lori iwe ipẹ̀jọ ti wọn fi n pe oludije si ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Osun.
Ẹni ti ọrọ naa soju rẹ, amọ ti ko fẹ ka darukọ rẹ sọ fun awọn akọrọyin ni ile Aarẹ wi pe, Aarẹ Buhari ti fi asẹ si pe, o di ẹyin idibo ki wọn to le fi iwe ipẹjo ransẹ si Sẹnetọ Adeleke.
Saaju ni ileesẹ ọlọọpa ti fi iwe pe Sẹnetọ Adeleke lati wa kawọ pọnyin ro ẹjọ lori ẹsun sise magomago lasiko idanwo, iwa ọdanran, lilo oruko ti ki n se ti ẹ, ati sise onigbọwọ fun ọdaran.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Alukoro ile ise ọlọọpa, Jimoh Moshood fi iwe pe sẹneto Adeleke ati awọn mẹrin miran lori ẹsun yi kan naa.
Ọlọ́pàá: Sẹ́nétọ̀ Adeleke gbọ́dọ̀ jẹ́jọ́ ẹ̀sùn jìbìtì ìdánwò
Lẹ́yin oṣu mẹrinla ti awọn ọlọpaa gbọ pe Sẹnetọ Ademọla Adeleke to jẹ oludije ipo gomina labe asia ẹgbẹ oselu PDP ninu idibo ipinlẹ Osun ṣe magomago ninu idanwo NECO ti 2017, ti o si gba ayederu iwe ẹri idanwo naa, wọn ti fẹ gbe lọ ile ẹjọ ni Abuja.
Ọlọpaa ni Sẹneto Adeleke ati awọn mẹta ti wọn fi ofin mu lori ẹsun naa ni awọn ti ṣetan lati gbe lọ si iwaju adajọ ni Ile Ejọ Giga ti ilu Abuja ni ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan, ọdun 2018. O wa nibi aṣekagba ipologo idibo ti ẹgbẹ rẹ PDP ni Osogbo. Sẹnetọ naa ti awọn eniyan ti mọ fun bi o ṣe maa n fi ijo dabira, fi ẹsẹ rajo ranpẹ nibi ipolongo naa.
Agbẹnusọ ọlọpaa ni orilẹede Naijiria Jimoh Moshood Wọn ti wa rọọ bayi lati farahan niwaju ọlọpaa fun anfani ara rẹ.
Moshood sọ ninu atẹjade kan ni ọjọ Ọjọru pe, "Adeleke forukọ sile lati ṣe idanwo NECO ni ọdun 2017, ṣugbọn ko yọju lati kọ idanwo naa botilẹ jẹ pe o gba iwe ẹri idanwo naa.
Moshood ni, "Ni ọjọ kọkanlelogun oṣu keje, ọdun 2017, ẹka ọtẹlẹmuyẹ ti ọlọpaa ni Ipinle Ọṣun gbọ wipe Sẹnetọ Ademola Adeleke ati Sikiru Adeleke n ṣe magomago idanwo ni ile iwe girama Ojo/Aro ni Osun.
"Nigba ti wọn de ile iwe naa, Sikiru Adeleke nikan ni wọn ri lori ijoko, ṣugbọn ko si Sẹnetọ Ademola Adeleke nibẹ. O jọ bi ẹni pe, o ti sa lọ ki awọn ọlọpaa o to de. Iwadi fi han wipe Sẹnetọ Ademola Adeleke forukọ silẹ lati ṣe idanwo NECO ti ọduin 2017. Oga agba ile iwe naa ati awọn olukọ meji lo ṣe elegbe lẹyin rẹ fun aṣemaṣe yii."
A gbọ pe, ọlọpaa fi panpẹ mu ọga agba ile iwe naa, Alhaji Aregbeṣọla Mufutau, olukọ to forukọ Adeleke silẹ, Ogbẹni Gbadamosi Ojo, ati olukan keji kan, Dare Olutope.
Moshood ni ọjọ mẹfa lẹyin rẹ - ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keje, ọdun 2017 ni awọn ọlọpaa mu ṣẹnetọ, ti wọn si mu Sikiru Adeleke ni ọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ, ọdun 2017.
O tun fi kun wipe ṣẹnetọ naa fi ọrọ silẹ wipe ni tootọ ni oun fi orukọ silẹ fun idanwo naa, ṣugbọn pe oun ko kọ ọ. Ṣugbọn o ni iwe ẹri idanwo naa to fi han pe o gba kirẹditi meje ati paasi kan.



















