NLC: Ìjọba ti gbà láti san owó oṣù mẹ́rin fáwọn òṣìṣẹ́ l'Ọ́ṣun

Awọn oṣiṣẹ nibi iwọde kan

Oríṣun àwòrán, Nigeria Labour Congress

Àkọlé àwòrán, Ijọba ni lootọ ni wọn yoo san owo oṣu mẹrin ninu mẹtalelọgbọn ti ijọba jẹ awọn oṣiṣẹ ati oṣiṣẹfẹyinti nipinlẹ naa

Ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ọṣun ni ijọba ipinlẹ naa ti gba lati san ajẹẹlẹ owo oṣu mẹrin ninu owo oṣu mẹtalelọgbọn ti wọn jẹ awọn oṣiṣẹ.

Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC nipinlẹ Ọṣun, Jacob Adekomi lo sọ eleyi ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba.

Ọpọlọpọ ariwo ni o ti n wọ tọ iye ajẹẹlẹ owo oṣu ti ijọba jẹ awọn oṣiṣẹ ni pinlẹ Ọṣun papaa bi eto idibo sipo gomina ni ipinlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn dokita n ṣe iwọde

Oríṣun àwòrán, Olu Alebiosu

Àkọlé àwòrán, Abajade ipade naa si ni pe ijọba yoo san ajẹẹlẹ owo oṣu mẹrin to ku ninu ọdun 2015 fawọn oṣiṣẹ

Awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ọṣun ti fi iwe ikede gbedeke ọlọjọ meje sita lopin ọsẹ fun ijọba lati san ajẹẹlẹ owo oṣu fawọn oṣiṣẹ abi ki wọn maa reti iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ laipẹ.

Jacob Adekomi ni alẹ ọjọ aje ni awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ijọba ṣepade nibi ti wọn ti fẹnu ọrọ jona lori rẹ.

Abajade ipade naa si ni pe ijọba yoo san ajẹẹlẹ owo oṣu mẹrin to ku ninu ọdun 2015 fawọn oṣiṣẹ, pẹlu ajẹẹlẹ ajẹmọnu owo isinmi ọdọọdun (leave bonus) fawọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ ati ibilẹ nipinlẹ naa.

Bakan naa ni wọn yoo tun san ẹkunrẹrẹ owo oṣu kẹjọ fawọn oṣiṣẹ pẹlu.

Àkọlé fídíò, Àwọn oṣiṣẹ feyinti ni Osun ṣé iwọde

"Bi wọn ba kọ lati san owo naa laarin asiko yii si ọjọ ẹti, o ṣeeṣe ki a pada si ẹnu gbedeke ọlọjọ meje ti a fẹ gunle o.

Gomina ti buwọlu aṣẹ fun sisan owo na wọn si ti jẹ ko di mimọ pe nigba ti a o ba fi ri ọla (ọjọbọ) awọn oṣiṣẹ yoo bẹrẹ si ni gba owo naa lori aṣuwọn ifowopamọ si wọn."

Nigba ti BBC Yoruba beere pe ṣe awọn eeyan ko ni maa fi oju ọgbọn oṣelu wo sisan owo naa lasiko yii ti ibo gomina ipinlẹ naa ku ọsẹ meji, alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC nipinlẹ Ọṣun naa ni ohun yoo wu ti awọn eeyan ba tumọ rẹ si, eyi to jaju fun oun ni ki awọn oṣiṣẹ ti oun n ṣoju o gba ẹtọ wọn.

Bakan naa lo ni idi ti o fi jẹ pe owo oṣu mẹrin ninu mẹtalelọgbọn ti ijọba jẹ ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ijọba f'ẹnuko si fun sisan ko ju pe 'lẹyin ọpọ ijiroro, a wo aṣuwọn ijọba, a ko si lee maa beere ohun ti wọn ko ni la fi ni ki a gba si oṣu mẹrin ọhun."

Amin iyasọtọ kan

Kini ijọba sọ lori adehun yii?

Gomina ipinlẹ Ọsun, Rauf Aregbesola

Oríṣun àwòrán, @raufaregbesola

Àkọlé àwòrán, Salinṣile ni bi oju ọrọ ti ṣe ri bayii, ko si idi fun ijọba ipinlẹ Ọṣun lati san aabọ owo oṣu mọ

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti fi idi ọrọ naa mulẹ.

Olori awọn oṣiṣẹ gomina nipinlẹ Ọṣun, Họnọrebu Rasaq Salinṣile ṣalaye fun BBC Yoruba pe lootọ ni ijọba ti gba lati san owo oṣu mẹrin ninu mẹtalelọgbọn ti ijọba jẹ awọn oṣiṣẹ ati oṣiṣẹfẹyinti nipinlẹ naa lẹyin ifikuluku pẹlu awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ.

Salinṣile ni bi oju ọrọ ti ṣe ri bayii, ko si idi fun ijọba ipinlẹ Ọṣun lati san aabọ owo oṣu mọ lẹyin eyi nitori ayipada rere to de ba eto iṣuna orilẹede Naijiria lapapọ ati paapaa julọ ipinlẹ Ọṣun.

Amin iyasọtọ kan

ASUP so iṣẹ́ rọ̀ ni iléẹ̀kọ̀ gíga mẹ́ta l'Ọ́ṣun

Ile ẹkọ giga gbogboun'se ipinlẹ Ọṣun
Àkọlé àwòrán, Iyanṣẹlodi awọn olukọ nileẹkọ giga yii n waye lẹyin bi ọsẹ kan lẹyin ti awọn olukọ nileẹkọṣẹ olukọni ni ilu Ileṣa naa ti gun le iyanṣẹlodi

Ile ẹkọ giga mẹta nipinlẹ Ọṣun ni wọn ti gbe ti pa bayii nitori iyanṣẹlodi awọn olukọ nibẹ.

Awọn olukọ labẹ aṣia ẹgbẹ olukọni ileẹkọ giga gbogbonise lorilẹede Naijiria, ASUP lawọn ileẹkọ giga gbogboniṣe nipinlẹ Ọṣun gunle iyanṣẹlodi naa lati fi ẹhonu han lori aisan owo oṣu mejidinlogun ti ijọba jẹ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ọ̀gá Bello: Àìgbọ́n ló ń da àwọn òsèré tíátà tó ń jà lórí ayélujára láàmú

Awọn ileẹkọ giga ti ọrọ kan ni ile ẹkọ giga gbogbonse Poly ipinlẹ Ọṣun ni ilu Iree, ileẹkọ giga imọ ẹrọ ni ilu Ẹsa oke ati ile ẹkọṣẹ olukọni to wa nilu Ila Ọrangun.

Iyanṣẹlodi awọn olukọ nileẹkọ giga yii n waye lẹyin bi ọsẹ kan ti awọn olukọ nileẹkọṣẹ olukọni ni ilu Ileṣa naa ti gu le iyanṣẹlodi.

Awọn oṣiṣẹ joko
Àkọlé àwòrán, Amọ, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti ni awọn ko tii gbọ nipa iyanṣẹlodi kankan.

Lẹyin ipade gbogbogbo ti wọn ṣe lọgba ile ẹkọ giga gbogboun'se ipinlẹ Ọṣun ni ilu Iree, agbẹnusọ fun ẹgbẹ awọn olukọni ile ẹkọ giga gbogboun'se lorilẹede naijiria, ASUP lawọn ileewe naa, Ọmọwe Jacob Adegbite ni igbesẹ awọn olukọni ọhunda lori ẹhonu wọn.

Awọn olukọni ile ẹkọ giga gbogbo-nse Poly naa n beere fun sisan ẹkunrẹrẹ ajẹẹlẹ owo oṣu wọn fun oṣu mejidinlogun ati gbogbo adehun to wa laarin awọn ati ijọba.

Amọ, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti ni awọn ko tii gbọ nipa iyanṣẹlodi kankan.

Kọmiṣọna feto iroyin nipinlẹ Ọṣun, Lani Baderinwa ni 'ijọba gomina Aregbeṣọla ko lee yẹ ipinnu rẹ lori alaafia awọn oṣiṣẹ'