Ademọla Adeleke ti kede pe oun ko ku o lẹyin tim ọrọ kan ti tan kaakiri pe o ti jade laye.
Adeleke ni oludije ti 'Jackson' wa ninu inagijẹ rẹ, ti o si jẹ oludijẹ ti iwọle rẹ taara sinu agbami oselu orileede Naijiria waye lẹyin igba ti ẹgbọn rẹ papoda.
Senetọ Nurudeen Ademola Adeleke, ni oludije ipo Gomina labe asia ẹgbẹ oselu Peoples Democratic Party, PDP, ninu idibo Gomina ipinlẹ Osun .
Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/Facebook
Àkọlé àwòrán, Adeleke ni oludije ẹgbẹ òṣèlú PDP nínú ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun
Ọdun ti orileede Naijiria gba ominira, 1960 ni wọn bi i ni ilu Enugu.
Bẹrẹ lati ori baba rẹ, Ayoola Adeleke, to jẹ Sẹnẹtọ ni saa isejọba oselu ẹlẹkeji, ẹgbọn rẹ naa, Isiaka Adetunji Adeleke, ti ọpọ eeyan mọ si ''Sẹrubawọn'' jẹ Gomina akọkọ lẹyin ti wọn da ipinlẹ Osun silẹ.
Oríṣun àwòrán, Osun Defenders
Nipa eto ẹkọ rẹ, a ri akọsilẹ pe:
Seneto Ademola Adeleke lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ niluEeko ati ile ẹkọ Nawarudeen nilu Ikire.
O lọ si ile ẹkọ Girama Adventist Secondary ni Ede ati Muslim Grammar school feto ẹkọ Girama.
Jacksonville ni Alabama lorileede Amerika lo ti kẹkọ nipa imọ eto ẹkọ nipa idajọ, iwadi iwa ọdaran ati eto oselu.
Abi ẹ n ro wi pe Jacksonville ni inagijẹ Jackson rẹ ti waye ni?
Irinajo Oselu rẹ
Lọdun 2017 ti ẹgbọn rẹ, Isiaka Adetunji ku, anfaani si silẹ fun Nurudeen Ademọla lati wọ agbami oselu taara.
O dije fun ipo asoju labe asia ẹgbẹ oselu PDP, lẹyin to kuro ninu ẹgbẹ APC.
Oríṣun àwòrán, @IsiakaAdeleke1
Àkọlé àwòrán, Ọmọ igbimọ ile asofin agba lori ọrọ idasẹsilẹ ati isẹ ilu ni Sẹnẹtọ Adeleke
Adeleke gbe igba oroke, ti o si jẹ asofin agba to n soju ni ile asofin agba labuja lọwọ-lọwọ yii.
Adeleke pegede gẹgẹ bi oludije fun ẹgbẹ oselu PDP ninu idije Gomina nipinlẹ Osun, lẹyin to fẹyin Akin Ogunbiyi janlẹ pẹlu ibo meje.
INTERACTIVETap or click to interact
Moshood Olalekan Adeoti
Action Democratic Party (ADP)
Kíni ọjọ́ ìbí yin?
Iṣẹ́ wo ni ẹ̀ ń ṣe?
Ìkádìí
A bí Moshood Olalekan Adeoti ni Ilú Ìwo, ijọba ibilẹ Iwo ní ìpínlẹ̀ Osun lọjọ́ kẹ́tàdínlogun oṣù kejì ọdún 1953
Ó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ ní District Council Primary Schoollọdun 1959 àti Aipate Day School lọdun 1964, lẹ́yìn náà ló lọ ilé ìwé Grammer lọdun 1974
Moshood Adeoti gboyè ìmọ ìṣòwò láti Fasiti Benin lọdún 1984
Moshood Olalekan Adeoti jẹ alága ẹgbẹ́ òṣèlú Alliance For Democracy 1998-2003, alága ẹgbẹ́ òṣèlú Action Congress 2006-2010 àti alága Action Congress of Nigeria ti alaga àkọkọ fún ẹgbk oselu APC 2010-2011
Isiaka Oyetola
All Progressives Congress (APC)
Kíni ọjọ́ ìbí yin?
Iṣẹ́ wo ni ẹ̀ ń ṣe?
Ìkádìí
Isiaka Adegboyega ti wọn bi ni ilu Iragbiji, ni ijọba ibilẹ Boripe ni ipinlẹ Ọsun.
Ọdun 1997 ni Oyetola ti darapọ mọ sise oselu, ati wipe o pẹlu awọn to da ẹgbẹ oselu Alliance for Democracy AD silẹ ni ọdun 1998.
Biotilẹjẹpe ogun ọdun niyi ti Oyetọla ti n se oselu, igba akọkọ ni yii ti yoo ma a dije du ipo labẹ ẹgbẹ oselu kan kan.
Amọ, iroyin kan ni wipe oun ni ẹyinoju Alaga Ẹgbẹ Oselu APC, Asiwaju Ahmed Tinubu ati Gomina Ipinlẹ Osun, Rauf Aregbesola
Alhaji Fatai Akinbade
African Democratic Congress (ADC)
Kíni ọjọ́ ìbí yin?
Iṣẹ́ wo ni ẹ̀ ń ṣe?
Ìkádìí
O darapọ mọ ilẹeṣẹ ijọba Ipinlẹ Ọṣun nibi to ti ṣiṣẹ fun ọdun mẹrindinlogun labẹ akoso ijọba oloogun mẹta ati ijọba alagbada Olagunsoye Oyinlọla.
Wọn yan Akinbade gẹgẹ bii akọwe ijọba Ipinlẹ Ọṣun nigba iṣakosi Olagunsoye Oyinlọla ni ọdun 2003.
O kede ipinnu rẹ lati gbe apoti ibo fun gomina ni ọdun 2010 laarin awọn oludije mẹrinla miiran, ṣugbọn ipinnu naa f'ori sanpọn.
Akinbade di oludije ẹgbẹ oṣelu ADC lẹyin ọsẹ meji to fi ẹgbẹ PDP silẹ.
Ademola Adeleke
People's Democratic Party (PDP)
Kíni ọjọ́ ìbí yin?
Iṣẹ́ wo ni ẹ̀ ń ṣe?
Ìkádìí
A bí Ademola Jackson Adeleke Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù karún-un ọdún 1960 ní ìpínlẹ̀ Enugu ní ìdílé sínatọ̀ Raji Ayoola àti Nnena Esther Adeleke ní ìlú Ede
Ó lọ sí iléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Methodist ní Surulere àti Nuwarudeen ní Ikire, bákan náà ló lọ iléèwé Seventh Day àti iléèwé Muslim Grammar ni ìlú Ede tí ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nípa ìwádìí ọ̀daràn ní Jacksonville State University Alabama USA.
Ó jẹ́ adarí àgbà ní iléeṣẹ́ Pacific Holdings Limited láti 2001 sí 2006 àti Quicksilver Courier Company ní Atlanta, Georgia láti 1985 sí 1989
Ademola Adeleke bẹ̀rẹ̀ òṣèlú ní ọdún 2007, ó sì dí sẹ́nétọ̀ tó ń sojú ẹkùn ìwọ̀-oòrùn Oṣun lẹ̀yìn ikú ẹgbọn rẹ̀ sẹ́nétọ̀ Isiaka Adeleke tó jẹ́ Gomìnà alágbádá àkọ́kọ́ ní ìpínlẹ̀ náà
Senator Iyiola Omisore
Social Democratic Party (SDP)
Kíni ọjọ́ ìbí yin?
Iṣẹ́ wo ni ẹ̀ ń ṣe?
Ìkádìí
Wọ́n bí Iyiọla Ajani Omisore sí ìdílé ọba ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹsàn án, ọdún 1957 ní ìlú Ilé-Ifẹ̀.
Omisore jẹ igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun, Adebisi Akande láàrin ọdún 1999- 2003.
Wọ́n dìbò yàn án sí ipò sẹ́nétọ̀ láti ṣojú ẹkùn ìdìbò ìlà oòrùn Ọṣun l'ábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP láàrin ọdún 2003 sí 2007, wọ́n tún padà dìbò yàn án ní 2007.
Ó díje fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun l'ọ́dún 2014 l'ábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, sùgbọ́n Rauf Aregbẹsọla fi ẹ̀yìn rẹ̀ janlẹ̀ nínú ètò ìdìbò nàá tó wáyé ní ọjọ́ kẹsàn án, oṣù Kẹjọ 2014.
Wo àwọn olùdíje
Ìkádìí
‘Dancing Senatọ’ni baba olorin Takasufe meji
Ti a ba ni ki a sọrọ nipa iriri rẹ nipa oselu, ko fẹ si ọrọ pupo ju wi pe, o bẹrẹ irinajo oselu pẹlu ẹgbọn rẹ, Isiaka Adeleke ni ọdun 2001.
Koda awọn to mọ ọ daada ni, Ademọla a maa saba tele ẹgbọn rẹ lo si ibi ipolongo oselu, ni ibi ti awọn to mọ ọ daada ni a ma fi ijo da ara.
Oríṣun àwòrán, @IAM_DAVIDO, @ISIAKAADELEKE1
Àkọlé àwòrán, Adeleke ni aburo baba gbajugbaja olorin Davido
O seese ko jẹ wi pe ibi ti inagijẹ rẹ ‘Dancing Sẹnẹtọ’ ti wa ye ree.
Adeleke jẹ aburo Baba gbajugbaja olorin takasufe, ti gbogbo aye mọ si Davido sugbọn se ẹ mọ wi pe, awọn ọmọ rẹ okunrin meji naa a ma kọ orin takasufe?
Sina Rambo ati B red lorukọ awọn ọmọ Ademọla mejeeji tawọn naa n kọ orin.
Oríṣun àwòrán, @iam_Davido
Àkọlé àwòrán, Ọmọ Adeleke T red jẹ olorin takasufe
Oríṣun àwòrán, @SINARAMBO
Àkọlé àwòrán, Orin kikọ jẹ atewọgba laarin awọn ọmọ okunrin mọlẹbi Adeleke
Ki a to gbagbe, onisowo ni Adeleke, ti o si ti fi igba kan jẹ oga ni ile ise Pacific Hoildings to jẹ́ ti ẹgbọn rẹ, laarin odun 2001 si 2016.
Saaju igba naa lo ti ba ile ise Quicksilver Courier Company lorileede America sisẹ gẹgẹ bi osisẹ́ fun igba ranpẹ.