Oyo SSG Office Burgled: Ìjọba Oyo dúnkookò mọ́ iléeṣẹ́ tó bá gbé ìròyìn èké síta

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ati ami idamọ ijọba Oyo

Oríṣun àwòrán, @seyimakinde

Idaji ọjọ ọdun ni iroyin kan gbalẹ pe awọn adigunjale ti ja wọ ọọfisi akọwe ijọba ipinlẹ Oyọ, Arabinrin Olubamiwo Adeosun lọjọbọ, tii se ọjọ aisun ọdun tuntun.

Gẹgẹ bi iroyin naa ti wi, eyi ti awọn ileesẹ iroyin kan gbe sita ( BBC Yoruba ko gbe iroyin naa tori ko si ọna lati fidi rẹ mulẹ nigba naa), wọn ni igba keji ree ti isẹlẹ naa yoo waye.

Iroyin naa ni akọwe ijọba ko si ni orilẹede yii lasiko ti isẹlẹ naa waye, ti wọn ko si tii mu ẹnikẹni lori isẹlẹ ọhun bi o tilẹ jẹ pe awọn agbofinro yi ọọfisi naa ka.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni iroyin ọhun sọ pe, awọn adigunjale yii tun fọ ọọfisi Akeem Ademola Ige, tii se oludamọran fun gomina Makinde lori eto ilera.

Ijọba Oyo sẹ lori iroyin to ni adigunjale fọ ọọfisi akọwe ijọba:

Amọ nibayii, ijọba ipinlẹ Oyo ti fesi pe iroyin eke gbaa ni iroyin naa nitori ko si ohun to jọ iru isẹlẹ bẹẹ rara.

Atẹjade kan ti akọwe feto iroyin fun gomina ijọba ipinlẹ Oyo, Taiwo Adisa fisita ni gbogbo awọn agbofinro to wa lọgba Secretariat lo fidi rẹ mulẹ pe ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun ni ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Oluwo Jogbodo Orunmila: Ẹsẹ odù Ifa ló fi ṣúre fún ọmọ Nàíjíríà ní àyájọ́ ọdún tuntun

"Awọn ileesẹ iroyin to gbe iroyin naa ni wọn ko se iwadii to yẹ nipa isẹlẹ naa, ki wọn to gbe sita, eyi to mu ki wọn kuna ninu ojuse wọn lati maa gbe iroyin ododo sita."

Bakan naa lo fikun pe awọn ileesẹ iroyin naa ko le sọ pato awọn dukia tawọn ole naa ji ko lọọfisi akọwe ijọba, eyi to fidi rẹ mulẹ pe omulomu ni wọn n mu.

Ijọba ipinlẹ Oyo wa dunkooko pe ileesẹ iroyin to ba gbe iroyin eke bii iru eyi yoo foju wina ofin nitori abala ofin wa nilẹ to de titẹ iroyin eke sita.

Àkọlé fídíò, Adejare Adeboye: Olúwa yóò dá gbogbo ohun ta sọnù ní 2020 padà ní ilọ́po méje fún wa

O ni ko si ileesẹ iroyin to dantọ ti yoo tẹ irufẹ iroyin ti ko fidi mulẹ bayii sita, eyi to le e ta ẹrẹ si asọ ala ijọba Oyo.