Nigerian universities resumption: Wó ọjọ́ ti àjọ NUC kéde pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásítì Nàìjíríà yóò wọlé

Ọpẹ o, ajọ NUC to n ri si ọrọ ile iwe giga fasiti lorilẹede Naijiria ti sọ fawọn giwa ile ẹkọ fasiti ni Naijiria pe ki wọn jẹ ki awọn akẹkọọ wọle pada lọjọ kejidinlogun oṣo kinni ọdun 2021 yii.
Ninu atẹjade kan ti NUC fi sita, ajọ naa ṣalaye pe wiwọle pada awọn fasiti wa ni ibamu pẹlu iyọnda ajọ amuṣẹya PTF lori coronavirus pe kawọn ileewe wọle.
O ti pe oṣu mẹsan tawọn akẹkọọ fasiti ti wa nile tori iyanṣẹlodi tawọn olukọ wọn gunle ati ajakalẹ arun covid-19.
- Wo ẹ̀bùn owó gọbọi tí Sanwo-Olu fún akẹ́kọ̀ọ́ tó gba ipò kínní ní fásítì LASU l'Eko
- Afeez Ọwọ: Èmi kọ́ ni mo kọ́kọ́ làwòrán Orisabunmi, ẹ ti ṣe wá rangun mọ́ mi?
- "Ikọ́ lásán ló pa Orisabunmi"
- "Ọjọ́ méjì péré ni Orisabunmi lò níléèwòsàn kó tó jáde láyé"
- Ẹ gbà mí o, wọ́n ti ń fi kóló mi kó àwọn èèyàn lómi ọbẹ̀ jẹ- Tawa Ajisefinni
- Yollywood: Kìí ṣe gbogbo ìgbéyàwó ló ń túká nítorí àgbèrè – Mide Martins
Loṣu kejila ọdun 2020 ni igbimọ PTF sọ pe ki awọn ileewe di ṣiṣi pada lẹyin ti wọn ti wa ni titi pa nitori ajakalẹ arun coronavirus.
Igbakeji akọwe agba ajọ NUC, Ọgbẹni Chris Maiyaki ṣalaye ninu atẹjade ọhun pe awọn ileewe naa gbọdọ tẹle awọn ilana ti ajọ NCDC la kalẹ lori ati gbogun ti arun coronavirus.
O ni kii ṣe igba akọkọ ree ti ajọ NUC yoo paṣẹ fawọn fasiti lati tẹle ilana kan tabi omiran.








