#BBCNigeria2019: Ètò tí mo ní fún Kwara yàtọ̀ sí ti ẹgbẹ́ ANRP ni mo ṣe fẹgbẹ́ wọ́n sílẹ̀

Olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú ANRP
Àkọlé àwòrán, "O pada han si mi pe ibi ti emi n lọ ati itẹsiwaju ti mo n wa fun ipinlẹ Kwara yatọ si ti awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa."
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Oludije fun ipo gomina ipinlẹ Kwara ninu ẹgbẹ oṣelu Abundant Nigeria Renewal Party, Yinka Ajia ti fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ.

Ninu ikede kan to fi si oju opo Facebook rẹ, Ajia sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun ko dije fun ipo gomina mọ, oun yoo ṣatilẹyin fun oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ APC, Abdulraman Abdulrazak ninu eto idibo naa.

Àkọlé fídíò, Yinka Ajia: ìbẹ̀rù Ọlọrun ni mo fẹ́ fi tukọ̀ Kwara ti mo ba wọlé
Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Lori idi to fi fi ẹgbẹ oṣelu ANRP silẹ ni ọjọ diẹ si idibo gomina, Ajia sọ fun BBC Yoruba pe oun fi ẹgbẹ ANRP silẹ nitori pe afojusun ati erongba ti oun ni fun awọn eniyan ipinlẹ Kwara yatọ si ti awọn olori ẹgbẹ oṣelu naa.

"Kiiṣe pe mo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, mo ri pe Abdulraman Abdulrazak ni awọn eniyan Kwara n fẹ, ni mo ṣe fẹ ẹ ṣatilẹyin fun un.

Ẹwẹ, o ni ireti oun ni pe awọn yoo jọ fi imọ kun imọ lori ipinnu awọn fun ipinlẹ Kwara lati mọ ibi ti oun ti le ran ijọba rẹ lọwọ.

"O pada han si mi pe ibi ti emi n lọ ati itẹsiwaju ti mo n wa fun ipinlẹ Kwara yatọ si ti awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa.

Emi o si fẹ ẹ jẹ alatako fun ipinlẹ Kwara nitori awọn eniyan mi jẹmi logun ju ẹgbẹ oṣelu kankan lọ.

Eyi lo mu ki n kọkọ kọwe fi ẹgbẹ naa silẹ ki n to bẹrẹ atilẹyin fun Abdulraman Abdurazak ti awọn ara ilu n fẹ."

Àkọlé fídíò, #NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí