2019 elections: Awọn jàǹdùkú yìnbọn f'éèyàn méjì nítorí owó ní Kwara

Nṣe ni ọrọ di pẹntuka, boolọ o yago fun mi nilu Ilọrin loru ọjọru mọ ọjọbọ ninu eyi ti eyan meji ọtọọtọ ti ṣe kongẹ ọta ibọn.
Wahala yii waye lagbegbe Adabata si Kuntu nigbati awọn olugbe ibẹ ni awọn janduku agbebọn kan ti wọn funra si pe wọn jẹ oniṣẹ iku awọn oloṣelu kan ya bo adugbo naa ti wọn si ba ọpọlọpọ dukia jẹ.

Nigba ti akọroyin BBC News Yoruba yoo fi de adugbo naa ni ọjọbọ nṣe ni gbogbo adugbo naa pa lọọlọ.

Ọpọlọpọ ọkọ ati sọọbu lawọn janduku naa bajẹ.

Ninu ọrọ tawọn olugbe adugbo naa ba BBC News Yoruba sọ, ija lori owo lo ṣokunfa rogbodiyan ọhun.









