2019 elections: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí pẹ̀lú ìbọn nípínlẹ̀ Ọyọ

Awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ ti mu awọn afurasi ọdaran kan ti wọn ka awọn ohun ija oloro mọ lọwọ
Kọmiṣọna ọlọpaa Shina Olukolu ni eyi jẹ afihan ara igbaradi ileeṣẹ ọlọpaa fun ipese abo lasiko idibo ọjọ abamẹta.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O ni ko si aniani pe awọn agbofinro ti tubọ jawe sobi lori eto abo nipinlẹ Ọyọ.
Gẹgẹbi o ṣe sọ, oju gbogbo yoo wa lara ipinlẹ Ọyọ lasiko idibo naa, idi si niyi ti ileeṣẹ ọlọpaa ko fi ni wọn ọn laabọ fun ẹnikẹni to ba fẹ da aṣọ iwa janduku, iwa ọdaran tabi jagidijagan kan ṣoro, ṣaaju tabi lasiko idibo naa.

Oniruru ohun ija oloro ati ọta ibọn ni awọn ọlọpaa naa ri gba mọ awọn afurasi naa lọwọ.
Bakan naa ni ọwọ tun tẹ arakunrin ọmọ ọgbọn ọdun kan pẹlu agbari eeyan lọwọ.
Afurasi naa ni agbẹ ati darandaran ni oun ṣugbọn awọn ọlọpaa ni lasiko ti o n bọ wa si ilu Ibadan, ni ọwọ palaba rẹ segi.









