R Kelly: Èmi kò jẹ̀bi ẹ̀ṣùn fífi ipá bá ọmọdé lòpọ̀

R kelly

Oríṣun àwòrán, CBS

Àkọlé àwòrán, R Kelly ń sukun lóri TV bó ṣe kọ ẹ̀sun ìfipábáni lòpọ̀

Olórin tàkasúfèé ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ń sunkún pẹ̀lú ìbínú lóri ẹ̀sùn pé, ó fi tipá banilòpọ̀ lásìkò to ṣe ìfòrọ̀wánilẹ̀nùwò àkọ́kọ́ lẹ́yìn to ti wà lágọ̀ọ́ ọlọpàá láti oṣù tó kọja.

''Emì ko ṣe ǹkan ti wọn ní mo ṣe. kìí ṣe èmi nìyí" ǹkan ti Kelly sọ niyi lásìkò tó ń ṣe ìfọ̀rọ̀wánílẹ́nuwò pẹlú ilé iṣẹ́ ìròyìn CBS, ó fi kún pé "mò ń gbìyànjú láti móríbọ nínú ẹ̀sùn yìí."

Ọwọ́ sìnkún àwọn agbófinro tẹ Kelly ní Chicago, pẹ̀lú ẹsùn oní kókó mẹ́wàá tó jẹ mọ ẹsun fífi ipá bá àwọn ọmọ mẹ́rin sùn, ti mẹ́ta nínú wọn sí jẹ ọmọde lásìkò ti ọ̀rọ̀ náà sẹlẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ó sọ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ti wọn fi kan òun kí wọn to yọ̀nda rẹ̀ lẹ́wọ̀n.

Tí R Kelly bá jẹ̀bi àwọn ẹsun ti wọn fi kàn án , ó ṣeeṣe kí ó lọ ẹwọn ọdun mẹ́ta sí méjé fún ẹsun kọ̀ọ̀kan.

Ìgbà míràn niyi lẹ́yìn èyí tó ṣẹ́lẹ̀ lọ́dun 2002, tí Kelly yoo kojú ẹsùn mọ́kànlélógùn tó fi mọ sísàfihan àworàn ìhòhò àwọn ọmọ kéèkéé, ti ọmọ kan nínú wọn si jẹ́ ọmọ kékeré

Sùgbọ́n àṣẹ̀yìn wá àṣẹ̀yìn bọ, adájọ nígbà náà sọ pé, kò si àrídájú pé ọmọ tó wà nínú fọ́nran ti wọn gbé yọjú sílẹ̀ ẹjọ jẹ ọmọ kékéré.

Wọn fẹnukò pé Kelly kò jẹbi ẹsùn kankan.

Awon olopaa àti Kelly

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, R Kelly ń sukun lóri TV bó ṣe kọ ẹ̀sun ìfipábáni lòpọ̀

Kelly sọ fún akọ̀ròyìn CBS Gayle King pé, wọn lo ẹsun ọjọsí gẹgẹ bíi 'gbèdéke fún ẹsun túntún tí wọn wé mọ òun lẹ̀sẹ̀.

Kelly ní "wọn padà sórí ẹsùn ti ó wáyé lọ́jọ́sí láti jẹ ki gbogbo ǹkan to ṣẹ̀lẹ̀ lásìkò yìí dàbi tòòtọ́ lóju àwọn ènìyàn."

Bákan náà ló tako ẹsùn ti wọn fi kàn nínú fónrán ti wọn pè ni Surviving R Kelly pé, ó kó àwọn obinrin pamọ lòdi sí ìpinu wọn, tó sì ń gba fóònù wọn, sàmójútó ounjẹ wọn, kò sì fún wọn láànfàní láti rí àwọn ẹbi wọn.

" A jẹ pé aṣiwere ni R Kelly, pẹ̀lú gbogbo ǹkan ti ojú mí ti rí, kí ń wá ma mú àwọn ọmọde lòdì si ìfẹ́ wọn, ''lo ọ̀pọ̀lọ ẹ,'' èyí ní Kelly sọ fun àkọròyìn níwájú ayawòràn.

''Gbàgbe nípa àwọn akọiroyin òfégé, gbàgbé nípa ǹkan to rò nípa mi. Kórira mí to ba wù ọ, fẹ́ràn mi tó ba wù ọ, sùgbọ́n lo ọpọlọ ẹ''

''Báwọ ni mó ṣe ya asìwere tó pẹ̀lú bí ǹkan ṣe ri láti ẹ̀yìn wá, àti gbogbo ǹkan ti mo ti là kọja, ṣe mó fẹ́ di aṣerubani ni, tí maa wá mú ọmọ obinrin lọ de wọn mọlẹ sí inú ilé kan?"

"Simi èré ṣíṣé, simi eré ṣíṣe, " bó se sọ èyí ló búsẹkún, "Kìí ṣe èmi ní èyí''

Lizzette Martinez jẹ́ọkan nínú àwọn òbinrin to nàka àlébu si R Kelly nínú fọ́nran Surviving R Kelly

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, R Kelly ń sukun lóri TV bó ṣe kọ ẹ̀sun ìfipábáni lòpọ̀

"Gbogbo yín ń gbìyànjú lati pa mí? Ǹkan ti Kelly sọ niyi.

Kelly gbà pé "mo ti ṣe àwọn ǹkan tí kò da tó pọ̀ pàápàá lóri ọ̀rọ̀ obìnrin" sùgbọ́n "Mo tọrọ aforijin lásìkò àwọn ajọṣepọ̀ nígbà náà."

Ó ní ìrírí òun pẹ́lú ìbálopọ̀ tipatipá gẹ́gẹ́ bíí ọmọde kò nípa lára òun, ti òun yóò fi wa má fi hùwa gẹ́gẹ́ bi àgbàlàgbà.

"Mó nílò ìrànlọ́wọ́," Kelly sọ fun King. Mo nílò ìrànlọwọ láti kọ mi ní ọ̀nà ti ǹ ko fi ni máá ṣe oore púpọ̀ nítori oore ti mò ń ṣe, ní àwọn eniyan fi ń jámi kulẹ̀ báyìí, ti mò sì ń dárijì wọn ní gbogbo igbà"

Sááju ní King ti ṣe ìfọ̀rọ̀wánílẹ̀núwò pẹ̀lú àwọn obìnrin méjì, Azriel Clary àti Joycelyn Savage, tí wọn n jẹ wọ́le-wọde Kelly lọ́wọ́lọ́wọ́.

Fọnran aworan kan fi ọ̀kan nínú àwọn obinrin náà, Clary to jẹ ọmọ ọdun mọ́kànlélógún hàn, bó ṣe ń sunkún lásiko tó ń satilẹyin fun olokiki akọrin náà.

Azriel

Oríṣun àwòrán, CBS

Àkọlé àwòrán, Kelly sọ pe Azriel Clary àti Joyceln Savage jẹ ọ̀rẹ́binrin òun

O ní " Mó ń sunkún, ẹ mọ òòtọ́," Ìrọ́ lásàn nítorí owó ní èyí"

Ẹ̀wẹ̀, àwọn òbi Alice àti Angelo Clary ti gbe àtẹjadé kan sita, tí wọn si tako iroyin to ni olokiki akọrin naa mu àwọn ọmọ àwọn pamọ, lòdì si ìfẹ́ inú wọn.

Sugbọn iroyin naa ni Azriel ní ààrùn ọpọlọ tó lágbàra, taa ba wo iru ìjìyà to ti rí lọ́wọ́ R Kelly. Wọn ni o seese ko ti ni ààrún ti wọn ń pè ní "Stockholm", tí ènìyàn yóò máà nífẹ̀ si ẹni to mú ní tipatipa.