Bílíọ̀nù kan náírà ni INEC ń san fún CBN àti ọmọogun oju òfurufú

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria
Bílíọ̀nù kan náírà ní àjọ elétò ìdìbò (INEC) yóò náá lóri kíkó àwọn ohun èlò ìdìbò ẹlẹgẹ́ pamọ si ilé ìfowopamọ àpapọ.
O tún wà fún gbígbé wọn lọ sí ìpínlẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹrìndínlógoji tó fi mọ olúlùú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Abuja pẹ̀lú ìrànwọ àwọn ọmọ ogun ojú òfurufú.
Bí INEC ṣe ń mójú tó kíkó àwọn ohun eèlò ìdìbò pamọ jákèjádo orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àwọn ọmọ ogun ojú òfurufú ń gba lọ si ìpínlẹ̀ ti wọn tọ́ sí.
Gẹ́gẹ́ bí iwé ètò INEC fún ìdìbò ọdun 2019 se ka rèé " ìpèsè owó fun ilé ìfòwópamọ àpapọ̀ fún kíko àwọn ohun eèlò ẹlégẹ́ pamọ́ to fi mọ́ owó àwọn ọmọ ogun ojú òfurufú N1,050,000,00
"Kíkó àwọn ohun èlò pamọ́ fún ìdìbò ni àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndílógójì àti olúlu Nàjíríà nínú ìdìbò mééjèjì na wa ni: N28,378,378.38"
Ọgá àgbà ọmọ ogun òfurufú, ti sọ lásiko tó ń ṣe àpérò pẹ̀lú àwọn oníròyìn ní'lú Abuja pé ọkọ òfurufú mẹ́jọ ni àwọn ti rán jáde láti gbé àwọn ohun eèlò ẹlẹgẹ́ lọ sí ibùdó ìdìbò wọn.
Ó fí kún un pé àwọn bàálú fó fun wákati òjìlélọ́ọdúnrún pẹ̀lú òsìṣẹ́ ọgọ́fà to fi mọ awakọ̀ ofurufu àti àwọn òṣìṣẹ́ amoju ẹ̀rọ míràn.












