Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ àwọn ọmọbìrin méjì tó pa b[pabá wọn

Oríṣun àwòrán, Pinellas County Sheriff's Office
Ọlọpaa ti mu awọn obinrin agbalagba meji to jẹ ẹgbọn ati aburo kan ni ni Florida ni orilẹede Amerika ti wọn fi ẹsun kan wipe wọn pa baba wọn to jẹ ẹni ọdun marundinlaadọrun nigba to ku ni ọdun 2015.
Aṣiri tu nigba ti arakunrin kan to jẹ ololufẹ tẹgbọn-taburo naa, Linda Roberts ati Mary-Beth Tomaselli, ta awọn ọlọpaa lólobó wipe ọkan lara wọn jẹwọ fun oun wipe awọn lo pa baba wọn.
Oṣu to lọ ni ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa wipe Linda to jẹ ẹni ọgọta ọdun ati Mary-Beth to jẹ ọdun mẹtalelọgọta lo pa baba wọn, ọdun mẹta lẹyin ti wọn pe ọlọpaa wipe baba wọn ṣa deede dakẹ ninu ile.
Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:
Ọga ọlọpaa agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ Bob Gualtieri sọ fun awọn oniroyin wipe ni ọjọ ti awọn obinrin naa pa baba wọn, wọn kọkọ fun ni ogogoro ati oogun orun mu. Nigba ti eyi ko pa baba, wọn fi irọri boo loju ko ma baa le mi.
Ṣugbọn igba ti igbesẹ keji yii naa ko pa baba wọn, wọn ti akisa aṣọ bọọ lẹnu ti wọn si fi ọwọ bo imu ati ẹnu rẹ ki o to wa ku. Awọn ọlọpaa sọ nigba naa wipe o dabi ẹni pe asiko baba ti to ni.
Ṣugbọn ni bayii, awọn tẹgbọn-taburo naa ti wa ni ihamọ ọlọpaa, nibi ti wọn yoo ti gbe wọn lọ ile ẹjọ. Ọlọpaa ni wọn pa baba wọn nitori wipe o kọ lati lọ gbe ile awọn arugbo nibi ti wọn fẹ ko lọ ku si.








