Kamaru Usman: Ǹ jẹ́ o mọ ìlú akẹ̀ṣẹ́ UFC yìí ?

Oríṣun àwòrán, Kamaru Usman
Orukọ Kamaru Usman lo gba ẹnu awọn ololufẹ ẹṣẹ kikan bayii lẹyin to di ọmọ ilẹ Afirika akọkọ lati gba igbanu ẹyẹ fun ẹṣẹ kikan ninu idije Ultimate Fighting Championship.
Ọmọ Amẹrika Tyron Woodley ni Usman din dundun iya fun to fi di ilumọọka akeṣẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Usman ti orukọ inagijẹ rẹ n jẹ Nigerian Nightmare lu ọmọ Amẹrika to jẹ alatako rẹ bi bara ninu ija ọhun niluu Las Vegas.
O ti di ija mẹrinla bayii ti Usman ti ja lai fidi rẹmi ninu ọkankan ninu awọn ija ọhun.
Ta ni akẹṣẹ Kamara Usman?
Ni ilu Benin ni wọn ti bi Kamaru Usman lọjọ kọkanla Oṣu Karun un ọdun 1987.
Baba rẹ jẹ sọja ti o si ṣiṣẹ pẹlu ile iṣẹ ologun orilẹede Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ẹbi Usman fi Naijiria silẹ lọ si orilẹede Amẹrika nigba ti o wa ni ọmọ ọdun mẹjọ.
Usman darapọ mọ awọn ti wọn n ṣe ere idaraya gidigbo lọdun keji to wọ ile iwe girama Bowie ni Arlington nipinlẹ Texas l'Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ija aadọta lo ti jawe olubori ninu ija mẹtalelaadọta ti o kopa ninu rẹ.
Lọdun 2012 ni Usman darapọ mọ ajọ ẹṣẹ kikan MMA, bẹẹ lo si bẹrẹ sii ja ni UFC lọdun 2015.
Iroyin sọ pe miliọnu mẹrinlelaadọta lo gba nigba to na Rafael dos Anjos loṣu kọkanla ọdun 2018, ṣugbọn ko si ẹni to mọ iye to gba ninu ija eleyi to ṣẹṣẹ ja yii.












