Kò sí ìwé ẹ̀rí fun olùdíje tí tó ba wóle lábẹ hílàhílo

yakubu

Oríṣun àwòrán, @inec

Àkọlé àwòrán, Mahmood ti fawon eeyan Naijiria lokan bale pe, didun losan a so ninu idibo 2019 nitori INEC a ṣiṣẹ bo ti yẹ

Àjọ elétò ìdìbò Nàìjíríà (INEC) ti ni kò sí ìwé ẹ̀rí fun olùdíje kankan tí ó ba jáwé olúbori lábẹ ìdìbo to ní hílàhílo.

O tun ni ajọ naa ko ni pin iwe ẹri fun ẹnikẹni to ba jawe olubori lasiko ti òṣìṣẹ́ eléto ìdìbò ba sọ èsì ìdìbò nítori pé ẹ̀mi rẹ̀ wà lábẹ́ ewu nínú níbi ìdìbò gómìnà tí yóò wáye lọ́la Satide, ọjọ kẹsàn osù Kẹ́ta, ọdún 2019.

Bákaǹ náà ni àjọ náà fi kún pé gbogbo ibi tí òṣìṣẹ́ INEC bá ti mọ̀ọ́mọ̀ maa lo ẹ̀rọ ayẹ káàdì ìdìbò wò ní àwọn yóò wọ́gilé ìdìbò wọn.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Akala lè ṣàtìlẹ́yìn fẹ́ni tó bá wù ú
Àkọlé fídíò, Ìbádọ́gba nínú ìsèlú àti iṣẹ́ láwùjọ ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsóké

Alága àjọ INEC, ọjọgbọ́n Mahmood Yakubu ló sọ èyí di mímọ lásìkò to ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn àjọ tó ni ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìdìbò tó fi mọ àwọn elétò ààbò lólú ìlé ìṣẹ́ INEC l'Abuja lánà

Yakubu ní " Ohun tó kọmilominú ni àwọn ǹkan eèlò ìdìbò tó fi mọ ẹrọ ayẹ káàdì ìdìbò, ìwé ìdìbò, ati àwọn ohun eèlò míràn tó sọnu nítóri àwọn ìwà ìpánle tó wáye láwọn ìpínlẹ̀ kan pàápàá jùlọ ìkọlù ti wọn ń se sí àwọn osìṣẹ́ elétò ìdìbò."

Àkọlé fídíò, BBC Yorùbá: Àwọn akọ̀ròyìn wa ti lọ káàkiri láti jábọ̀ ìròyìn ìbò

"Ọ̀pọ̀ àwọn òsìsẹ́ wa ní wọn jígbé pamọ́ lójùnà àti da ètò ìdìbò rú tábi ṣe màgòmágó sí abájade èsì ìbò, kódà àwọn àtundi ìbò tí yóò wáye jẹ́yọ látàrí àwọn ìdí wọnyí.

"Ẹ̀wẹ̀ àjọ INEC kò ni fọ́wọ́leràn láti máà woran kí wọn máà jí òṣìṣẹ́ àjọ náà gbé pamọ tàbí mú wọn ni dandan láti kéde ẹni to jáwé olúbori nínú ìbẹ̀rù bojo, nítori naa àjọ wá ko ni máa san ẹsan fún aburu láti máa kéde'pé wọn jáwe olubori.''

Àkọlé fídíò, #NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí

Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ ìpínlẹ̀ mọ́kàndínlọgbọ̀n ní ìdìbò gómìnà yóò ti wáye tí wọ́n yóò sì dìbò yan ènìyàn ẹgbẹ́rún kàn ó dí mẹ́sàn sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin nígbogbo ìpínlẹ̀ pátápáta, alága mẹ́fà àtí kànsẹ́lọ mẹ́jìlélọ́gọ́ta ní olú ìlú Nàìjíríà l'Abuja.

Àkọlé fídíò, Nigeria Election 2019: Ará Eko pariwo ohun márùn-ún tí wọn ń fẹ́ lọ́wọ́ ìjọba tó ń bọ̀

Ajọ náà yóò tún ṣe àtúndi ìbò ní ìpínlẹ̀ mẹ́rìnla àti ẹkún ìdìbò mẹ́rìnlélógún.