2019 elections: PDP kẹ̀yìn sí Kashamu, wọ́n ní kọ́mọ ẹgbẹ́ ó dìbò fún Akinlade olùdíje APM l'Ogun

Sẹnetọ Kashamu

Oríṣun àwòrán, @Sen_Kashamu

Àkọlé àwòrán, Eyi ko ṣẹyin aawọ to n waye fun laaarin Sẹnetọ Buruji Kaṣamu ati Ladi Adebutu lori tani yoo oludije ti ẹgbẹ oṣelu naa fọwọ si

Awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun ti paṣẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lati dibo wọn fun oludije ẹgbẹ oṣelu APM ninu idibo gomina ti yoo waye lọjọ abamẹta.

Eyi ko ṣẹyin aawọ to n waye fun igba pipẹ laarin ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun lori ta gan ni oludije ti ẹgbẹ fọwọsi laaarin Sẹnetọ Buruji Kaṣamu ati Ladi Adebutu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Niwọn igba ti ile ẹjọ si tun ti buwọlu Sẹnetọ Buruji Kaṣamu gẹgẹ bii oludije ti ajọ eleto idibo INEC gbọdọ da mọ eyi ti ko dun mọ awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa ninu, ni wọn fi da ifa kaka k'eku maa jẹ sese ko kuku fi ṣe awadanu lori ọrs tani ki wọn dibo gomina fun fun.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Afọlabi Orẹkọya to jẹ amugbalẹgbẹ fun Ladi Adebutu ṣalaye pe ni ọsan ọjọbọ lawọn adari ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Ogun fi ẹnu ko nibi ipade ti wọn ṣe nibẹ ni wọn si ti paṣẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP pe Adekunle Akinlade ni ki wọn dibo fun gẹgẹ bii gomina ni ipinlẹ naa.

Nigba ti BBC News Yoruba beere ọrọ nipa oludije PDP ti ofin mọ, iyẹn Buruji Kaṣamu, wọn ni loju awọn ọmọ ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ogun, Kaṣamu kii ṣe oludije PDP, iṣẹ ara rẹ lo n jẹ kiri.