Ìpànìyàn l'Eko: Ilé ẹjọ́ dá ẹjọ́ ikú fún ọkùnrin tó pa ìyàwó rẹ̀

EKO

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fẹ̀sùn kan Lekan Shonde pé ó lu ìyàwó rẹ̀ pa, lẹ̀yín to fi ẹ̀sùn kan pé iyawo rẹ̀ pé óún yan àlè.

Ile ẹjọ giga ti da ẹjọ iku fun ọkunrin kan, Lekan Shonde to lu iyawo rẹ Ronkẹ pa, ni bii ọdun mẹta sẹyin.

Onidajo Agba, Josephine Oyefeso lasiko to n se idajọ naa ni Ọjọ Ẹti sọ wi pe o jẹbi ẹsun ẹyọkan ti ijọba ipinlẹ Eko fi kan an.

Adajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko ni gbogbo ẹri fihan wi pe lootọọ ni Lekan Shonde pa iyawo rẹ Ronke.

Àkọlé fídíò, Ìbádọ́gba nínú ìsèlú àti iṣẹ́ láwùjọ ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsóké

Ọdun mẹta sẹyin ni iroyin gbe e wi pe ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelaadọta kan ti lu iyawo rẹ pa ni ile wọn ni agbeegbe ẹgbẹda-idinmu ni ipinlẹ Eko.

Wọn ni ọkunrin naa ti ilẹkun mọ oku iyawo rẹ pẹlu awọn ọmọ meji ko to di wi pe ọmọ ọdọ wọn wa lọ fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa.