2019 Nigeria Election: Àgbùnbánirọ̀ pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbà ọkọ̀ ojú omi l'Ondo

Agunbanirọ

Oríṣun àwòrán, NYSC

Àkọlé àwòrán, Iku agunbanirọ

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe agunbanirọ kan, Ibrahim Okanlawon to ṣiṣẹ pẹlu ajọ eleto idibo INEC ninu ibo gomina ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ lagbegbe Ewerebubou, wọọdu Arogbo ni ipinlẹ Ondo padanu ẹmi rẹ.

Iroyin naa tun sọ pe agunbanirọ miran tun ti dero ile iwosan nipinlẹ Ondo kan naa.

Okanlawọn ni o padanu ẹmi rẹ nigba ti ọkọ oju omi ti wọn wọ pada si ibugbe wọn doju de lẹyin idibo ọjọ nirọlẹ ọjọ Satide.

Àkọlé fídíò, APC jáwé olúborí nípínlẹ̀ Ekiti

Ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ni ruru omi ati iji lile lo da ọkọ oju omi naa nu.

Ẹwẹ, igbakeji gomina ipinlẹ Ondo Ọgbẹni Agboola Ajayi ti ranṣẹ ikẹdun si ẹbi agunbanirọ to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Àkọlé fídíò, BBC Yorùbá: Àwọn akọ̀ròyìn wa ti lọ káàkiri láti jábọ̀ ìròyìn ìbò

Awọn meje miran ti ori yọ ninu iṣẹlẹ ọhun n gba itọju nile iwosan bayi.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Akala lè ṣàtìlẹ́yìn fẹ́ni tó bá wù ú
Àkọlé fídíò, Diaspora: Ẹyin nikan kọ́ ni ọ̀rọ̀ idibo Naijiria kàn nílé