New Minimum wage: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ní Jan. 8

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria ti ni awọn ni ẹbun nla fun orilẹ-ede Naijiria bi ijọba apapọ atawọn ijọba ipinlẹ ba kuna lati fi ẹnu ọrọ ẹkunwo oṣu tuntun jo ibikan ṣaaju gbendeke ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2018.
Nisinyi ti gbendeke naa ti kọja ti ọdun tuntun ti wọle bayii, ibeere to gbẹnu ọpọ onwoye ni irufẹ ẹbun wo ati pe ọna wo ni ẹbun yii yoo gba wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Amọṣa, akọwe agba ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, Peter Ozo-Esan ti ṣalaye pe gbogbo ẹgbẹ oṣiṣẹ ti bẹrẹ igbesẹ lati gbe iwọde ti yoo se ilẹkun mọ gbogbo ohun amuṣọrọ aje orilẹ-ede Naijiria bẹrẹ lati ọjọ kẹjọ, oṣu kinni,
ọdun 2019.
Ozo-Esan ni ko si ohun to kan ẹgbẹ oṣiṣẹ pẹlu igbimọ amuṣẹya ti aarẹ tun ni oun yoo gbe kalẹ lori ọrọ ẹkunwo oṣu tuntun naa.
O ni ko si ohun meji ti ẹgbẹ oṣiṣẹ n fẹ bayii ju ki aarẹ fi aba lori ẹkunwo oṣu naa ṣọwọ sawọn aṣofin apapọ fun bibuwọlu ki iṣẹ lee bẹrẹ lori sisan rẹ.










