Minimum Wage: Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ TUC fárígá sí ìjọba Naijiria lórí owó oṣù tuntun

osise

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, ẹgbẹ oṣiṣe yari fun ijọba Naijiria

Laarin oṣu karun un ọdun 2019 ni ijọba Naijiria gbe igbimọ kan kalẹ lati mojuto ọrọ afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ.

Ogbeni Richard Egbule to jẹ alaga igbimo naa lo kede aṣẹ tuntun ti Aarẹ Muhammadu Buhari pa yii fawọn oniroyin.

Igbimọ naa ti wọn pe ni National Salaries Income and Wages Commission ni wọn ti ṣe iṣẹ wọn tan.

Aarẹ Buhari ti ni ki wọn bẹrẹ si ni san owo yii lati oṣu kẹrin ọdun fawọn ti ọrọ kan.

Loṣu kọkanla ọdun 2018 ni aarẹ Buhari ni oun a gbe abadofin naa siwaju ile ni eyi ti awọn aṣojuṣofin sọ di ẹgbẹrun mẹtadinlọgbọn ninu ijokoo wọn.

Oṣu kẹta ọdun 2019 ni awọn aṣofin agba tẹwọ gba sisan ẹgbẹrun lọna ọgbọn ti wọn si fọwọ sii gẹgẹ bii owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

Oloye Egbule ni wọn yoo bẹrẹ si ni san owo oṣu tuntun yii lati ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2018 ni awọn ileeṣẹ ijọba apapọ bi o ṣe yẹ.

aare

Oríṣun àwòrán, @Presidency

Àkọlé àwòrán, Minimum Wage: Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ TUC fárígá sí ìjọba Naijiria lórí owó oṣù tuntun

Titi di asiko yii ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti fariga pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ni ti ijọba ba kọ̀ lati mu ileri wọn ṣẹ lori eyi ti wọn fẹnuko le lori tẹlẹ.