Onnoghen: Nítorí EFCC, ìgbìmọ̀ ìṣèdájọ́ tó ga jùlọ, NJC kọ̀wé ìfisùn tuntun ránṣẹ́ sí Onnoghen

Walter Onnoghen

Oríṣun àwòrán, concisenews

Àkọlé àwòrán, Ìgbìmọ̀ ìṣèdájọ́ tó ga jùlọ, NJC ní àwọn yóò pàdé lọ́jọ́rú láti yẹ àbájáde rẹ̀ wò.

Igbimọ idajọ orilẹede Naijiria, NJC ti kọ iwe tuntun ranṣẹ si adajọ agba orilẹede Naijiria, ti wọn ni ko lọ rọọkun nile fun igba diẹ, Walter Onnoghen lati wa wi tẹnu rẹ lori iwe ẹsun tuntun ti ajọ to n risi iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC kọ ranṣẹ si igbimọ naa n itori Onnoghen.

Ni ọjọ aje ni igbimọ naa gbe igbesẹ ati kọwe naa nibi ipade pajawiri to ṣe nilu Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbimọ naa tun pinnu lati gbe igbimọ alabẹṣekele kan kalẹ lati wo awọn ẹsun ti wọn fi kan Onnoghen ati adele adajọ agba, Tanko Muhammad.

Igbimọ NJC ti kọkọ kọwe ranṣẹ si awọn adajọ agba mejeeji yii nibi ijoko rẹ lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kinni ti wọn si fun wọn ni gbedeke ọjọ meje lati dahun si ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Àkọlé fídíò, 'Gbogbo olùdíje Ogun fi dá àwọn ènìyàn lójú pé...'

Alukoro igbimọ iṣedajọ agba orilẹede Naijiria, Sọji Oye ni igbims naa tẹwọ gba iwe ifisun tuntun latọdọ ajọ EFCC lo faa ti wọn fi tun kọwe pada si adajọ agba naa lati fi esi sii laarin ọjọ meje.

O ni ọjọru tii ṣe ọjọ kẹtala oṣu keji ọdun 2019 ni igbims naa fi ipade si lati tẹwọ gba abajade iṣẹ igbimọ alabẹ ṣekele ti wọn gbe kalẹ lori rẹ ni ibamu pẹlu abala kẹtadinlogun iwe ofin igbimọ iṣedajọ to ga julọ lorilẹede Naijiria.