Àwọn àwòrán àwòmáleèlọ ní ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùba ti Ogun

Ẹ fójú yín lóúnjẹ pẹlú àwọn àwòràn láti ibi ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ láàrín àwọn olùdíje gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ogun.

awọn akopa
Àkọlé àwòrán, Ajimuna ni awọn akopa fi ṣe, ki eto to bẹrẹ ni wọn ti n de sibi ipade lati forukọ silẹ
Ori itage ninu gbọngan ipade
Àkọlé àwòrán, Ori itage ninu gbọngan ipade ti wa ni tito lowurọ kutu hai ti awọn sgbohunsafẹfẹ ati amoju ẹrọ naa si ti bẹrẹ iṣẹ ki ohun gbogbo le lọ leto leto bi eto ba bẹrẹ
Ademola Ogunbanjo
Àkọlé àwòrán, Ademola Ogunbanjo ni ki awọn eniyan tu yaya ki wọn lọ gba kaadi idibo wọn ki wọn si rii pe wọn dibo wọn tori ijọba tiwa n tiwa kii ṣe adanikan ṣe
Awọn akopa
Àkọlé àwòrán, Awọn akopa n forukọ silẹ
Akinlade Adekunle
Àkọlé àwòrán, Akinlade Adekunle ti ẹgbẹ oṣelu APN ni tẹẹ ba ti dibo yin ki ẹ duro ki wọn ka a tori oju awo
Gbọngan ṣaaju ipade
Àkọlé àwòrán, Gbọngan ṣaaju ipade lowurọ kutu hai pẹlu awọn ẹbun ọlọkan o jọ kan ti ile iṣẹ BBC Yoruba ti pese silẹ lati mọ riri pe awọn akopa wa sibi ipade ifọrọwerọ
Gboyega Nasir Isiaka
Àkọlé àwòrán, Gboyega Nasir Isiaka ti ẹgbẹ oṣelu ADC ni ọrọ idibo kan ara ile o kan ara oko ati pe ẹgbọn, iya, baba ati aburo ni gbogbo awọn ti awọn n dibo ki wọn pawọpọ jẹ ko yọri si rere ki ipinlẹ Ogun ma baa jo ajorẹyin.
Atọkun eto
Àkọlé àwòrán, Atọkun ni ibẹrẹ eto fun awọn oludije ni iṣẹju diẹ lati sọ ọrọ akọkọ wọn fun awọn ti yoo dibo yan wọn.
Awọn oṣiṣẹ alaabo
Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ alaabo duro wamu wamu lẹnu ibode ati ninu gbngan igbalejo lati rii pe abo to daju wa.
Paṣeda
Àkọlé àwòrán, Paṣeda ti ẹgbẹ oṣelu SDP wọle lẹyin iṣẹju diẹ ti eto bẹrẹ.
Awọn akopa akanda
Àkọlé àwòrán, Kii ṣe ti ka kan sọrọ pẹlu lati tako ra ẹni. Ṣe lawọn oludije n dẹrin pẹkẹ awọn akopa
Ori itage ninu gbọngan ipade
Àkọlé àwòrán, GNI ati Ademọla Ogunbanjọ lori itage
Awọn akopa
Àkọlé àwòrán, Awọn akopa bu sẹrin nigba ti awọn oludije n sọrọ lati fa oju awọn araalu mọra
Gbọngan igbalejo
Àkọlé àwòrán, Fọfọ ni inu gbọngan igbalejo kun
Asiko ibeere
Àkọlé àwòrán, Asiko ibeere fun awọn oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ogun
Awọn oludije
Àkọlé àwòrán, Awọn oludije kọkọ tahun sira wọn wọn si tun dọwẹkẹ loju agbami eto
Lẹyin ifọrọwerọ
Àkọlé àwòrán, Awọn oludije duro papọ lẹyin ifọrọwerọ
awọn oludije lẹyin ifọrọwerọ
Àkọlé àwòrán, "Ọrẹ la o maa ṣe. Ẹgbọn ati aburo ni awa oludije" lo n sọ itumọ aworan awọn oludije yii lẹyin ifọrọwerọ.
Kikọ orin orilẹede Naijiria
Àkọlé àwòrán, Gbogbo eto lọ bo ṣe yẹ ko ri laarin awọn oludije ati awọn akopa. Orin orilẹede Naijiria ni wọn fi kasẹ eto nilẹ.