Gani Adams: Kò bá dáa tí INEC bá sùn ọjọ́ gbígba PVC síwájú

Bi o ti ṣe ku wakati perete ki gbedeke gigba kaadi idibo PVC lorileede Naijiria pari, Aarẹ Ọna kakanfo ilẹ Yoruba Gani Adams ti funpe ki ajọ INEC sun ọjọ gbigba kaadi naa si waju.
Alaye to fi siwaju fun arowa yi ni pe pupọ ninu ọmọ orileede Naijiria ni ko ti ri kaadi idibo wọn gba.
O wa ni ki INEC sun ọjọ kaadi gbigba naa siwaju titi di ọjọ isẹgun tii ṣe ọjọ kejila oṣu keji nitoripe ipolongo idibo yoo si waye titi di ọjọbọ tii ṣe ọjọ kẹrinla.
'Airi kaadi yi gba yoo se akoba fun awọn to fẹ dibo.Bi kii ba ṣe wi pe mo figbe sita,emi gaan ko ba ma ni anfaani lati ri kaadi mi.'
Gani Adams ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ile iṣẹ BBC so pe o ti to ọjọ mẹta ti ohun ti n gbiyanju lati gba kaadi idibo fun ara ohun ati iyawo ohun.
'Mo ni lati sọ fun awọn oṣiṣẹ INEC nilu Eko pe mo ti fi atẹjade sita sawọn oniroyin nipa kaadi mi ti mi o ri gba ki wọn to sare mu wa fun mi nile mi lowurọ ọjọbọ.''
Aarẹ Onakakanfo ni 'boya nitori mo jẹ ilumọka ni wọn fi mu kaadi mi wa.Ti iru ẹmi ba ni lati pariwo sita ki n to ri kaadi mi gba,ki wa ni yoo ṣẹlẹ si awọn mẹkunu lawujọ?'
Ọjọ kẹsan Oṣu keji ni gbedeke ti Inec fi kale fun gbigba kaadi idibo yoo pe.
Lalai ni kaadi lọwọ,Inec ti ni awọn ko ni gba ẹnikẹni laaye lati kopa ninu idibo ọdun 2019.












