Inec Oyo: Kò sí olóṣèlú tó fẹ fí owó rà káàdì lọwọ wà

Awọn kaadi idibo

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria

Àkọlé àwòrán, Iye kaadi idibo ti awọn eeyan ko tii gba n kan ọpọ lominu

Alakoso ajọ eleto idibo nipinlẹ Oyo Mutiu Agboke ti tako iroyin kan to gbode pe o sọ pe awọn oloṣelu n fi owo daamu ohun lati ta kaadi idibo fun wọn.

O salaye yi ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Yoruba

Agboke ni ọtọ ni ohun ti oun sọ ati wi pe ''o ya mi lẹnu pe awọn akoroyin kan gbe iroyin ohun ti mi o sọ sita''

''Nkan ti mo sọ ko ni iwe iroyin yẹn gbe jade.Awọn eeyan lo tami lolobo nigboro wi pe wọn ni mo sọ wi pe awọn oloselu n fi owo damu mi.''

O fikun wi pe ''oun ti mo sọ ni wipe kaka ki ọpọlọpọ oloselu pawọ pọ pẹlu wa lati ri wi pe awọn oludibo gba kaadi to pọ nilẹ, kaadi ti ko si ni tita ni wọn wa kaakiri.

Nipa kaadi ti o wa nilẹ, o tẹnumọ bo ṣe ṣe pataki ki awọn ara ilu wa gba kaadi wọn saaju idibo.

''Kaadi ti awọn eeyan ti gba lọdọ wa ti to 240,000 ti a si ni akọsilẹ pe eyi ti wọn ko ti gba ju 900,000 lọ.''

''Idi ti a fi ni ki awọn oloselu ke si awọn eeyan lati wa gba kaadi re.Eni ti ko ba ni kaadi ko le ni anfaani lati dibo nitori Inec ti fagile lilo foomu 'incidence' ti a ma n lo tẹlẹ ti kaadi ko ba si tabi ti ko ṣisẹ''

Àkọlé fídíò, Wòlíì Kasali sọrọ nípa awuyewuye pé o lè ìyàwó rẹ̀ jáde nílé
Àkọlé fídíò, INEC yoo sun miliọnu meje kaadi idibo

O ko le dibo pẹlu kaadi ti kii ṣe ti ẹ

BBC Yoruba bere lọwọ ogbẹni Mutiu pe kini yoo ṣẹlẹ si awọn kaadi ti ara ilu ko ba wa gba.

Alaye to ṣe ni wi pe awọn yoo da irufẹ kaadi bẹ pada lọ si ẹka ijọba ipinlẹ Inec lati ijọba ibilẹ ni kete ti idibo ba ku bi ọsẹ kan.

''Bi eeyan ba ti lẹ ri kaadi onikaadi gba ko le sanfani fun nitori ko ni le fi dibo. Ohun to pe Inec ni ki awọn eeyan wa gba kaadi wọn ki eto idibo baa le lọ deede.''