Jack Ma: A ti gbe igbesẹ̀ lori tita PVC lori Alibaba

Kaadi Idibo

Oríṣun àwòrán, Alibaba

Àkọlé àwòrán, Awọn kaadi idibo Naijiria ti awọn kan n ta lori ile itaja ayelujara Alibaba.

Gbajugbaja oniṣowo ọmọ China ni, Jack Ma, to jẹ oludasilẹ ile itaja ayelujara ti a mọ si Alibaba, ti gbe igbesẹ lori awọn kan ti wọn ta kaadi idibo Naijiria (PVC).

Lẹyin ti ikọ BBC beere oun ti ileeṣẹ naa n ṣe lori awuyewuye to waye nipa kaadi idibo ti wọn n ta lori Alibaba, ileeṣe naa fesi wipe, ni kete ti awọn gbọ nipa ọrọ naa ni awọn yọ awọn kaadi naa lori atẹ Alibaba.

Ileeṣẹ naa sọ fun BBC pe, "A ko gba tita awọn oun ti o lodi si ofin lori Alibaba, bẹẹni a ko gba iwakiwa laaye. A o tubọ maa gbe igbesẹ lati dẹkun awọn iwa ti ko tọ bayi,."

Ni ana naa, ni Atiku Abubakar, ti o jẹ oludije fun ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP rọ Jack Ma ki o tiraka lati ri pe, wọn ko lo ileeṣẹ oun lati da oju ijọba tiwan-tiwa ru ni orilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, INEC yoo sun miliọnu meje kaadi idibo

Awọn alaṣẹ ajọ eleto idibo (INEC) tun ṣalaye idi ti awọn ọmọ Naijiria ko ṣe ni lati foya bi awuyewuye se waye nigba ti wọn ri pe awọn kan n tan kaadi idibo lori ile itaja ayelujara Alibaba.

Ọga ileeṣẹ INEC to n ṣakoso ilanilọyẹ̀, Oluwole Osaze-Uzzi, ti kọkọ gbe atẹjade kan sita ninue eyi to ti ṣalaye pe ajọ INEC ti n gbe igbesẹ lati dẹkun tita kaadi idibo naa.

Ṣugbọn nigba ti ikọ BBC baa sọrọ, o ṣalaye pe, ko sewu rara o, nitori pe, awọn irinṣẹ́ INEC (card reader) to n ba ojulowo kaadi idibo ṣiṣẹ́ yoo kọ awọn tọ jẹ́ ayederu.

Idibo 2015 ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn eniyan n ke gbajare pe iru eyi le fa ọpọlọpọ ṣiṣe eru nidi ibo.

Lori ibeere pe boya wọn le fẹ da awọn kaadi idibo ti wọn ba lọ ra ni China pọ̀ mọ́ awọn ti atijọ ti irinṣẹ ko le ba ṣiṣẹ́ mọ, o ni iru rẹ ko le waye.

Awọn eniyan n ke gbajare pe iru eyi le fa ọpọlọpọ ṣiṣe eru nidi ibo.

Awọn nọmba idanimọ fun awọn ojulowo kaadi idibo naa nkọ? Ṣe ko ṣeeṣe ki awọn onijibiti ẹda kan ni ileeṣẹ INEC ti fun awọn ti o n tẹ ayederu kaadi? Osaze-Uzzi ni ko si bi iru rẹ ṣe le ṣẹlẹ̀.

O ni, "A mọ pe awọn kan ti n gbimọ lati lọ maa ṣe awọn ayederu kaadi idibo. Sugbọn tẹ ba woye, ẹ o ri pe kon si awọn orukọ awọn eniyan lori wọn. Ọpọlọpọ awọn oun idanimọ ni a ti ṣe sinu awọn ojulowo kaadi idanimọ ti awọn ayederu ko le ni. Awọn ti o si n ṣe awọn kaadi naa ko le mọ awọn nkan wọnyi."