Buhari: Emi ko ni fontẹ lu atunse ofin idibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi iwe ransẹ sile asofin apapọ ilẹ Naijiria pe oun ko ni fontẹ lu atunse ofin idibo ti wọn se laipẹ yii.
Olori ile asoju-sofin, Yakubu Dogara lo ka iwe ti Buhari kọ setigbọ awọn asofin lasiko ijoko ile lọjọ isẹgun.
Buhari ni atunse ofin idibo naa lo ngba ojuse ti ofin ilẹ wa gbe le ajọ eleto idibo (INEC) se, gẹgẹ bo se kan ọrọ eto idibo, to fi mọ mimu ọjọ idibo ati bi wọn yoo se to ọjọ ti idibo yoo waye.
Bakanna o ni bi oun se kọ lati fọwọsi atunse ofin idibo naa lo wa nibamu pẹlu ori kejidinlọgọta ofin ilẹ wa tọdun 1999, paapa ẹsẹ kẹrin ofin naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

"Atunse abala kejidinlogoje ofin ilẹ wa eyi to wa lati wọgile awọn opo meji tawọn oludije fi lee tako esi idibo, ni yoo gbegidina awọn ẹtọ irufẹ oludije bẹẹ si agbeyẹwo ilana eto idibo."
Bakanaa lo ni atunse ofin ori kejilelaadọjọ ofin ẹsẹ okoolelọọduntun ati marun ninu ofin ilẹ wa lo npe ile asofin apaps nija lori agbara ti wsn ni lori eto idibo ijọba ibilẹ.








