Àwọn jàǹdùkú sọ Ààrẹ Buhari, Dapọ Abiọdun lókúta nílùú Abẹokuta

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad
Yanpọnyanrin bẹ silẹ nibi ipade ipolongo ibo ti ẹgbẹ oṣelu APC ṣe ni ipinlẹ Ogun nibi ti aarẹ Muhammadu Buhari ati ikọ ipolongo rẹ ti n polongo ibo aarẹ ti yoo waye ni ọjọ abamẹta ọsẹ yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bi awọn ero ti ṣe wa ni gbagede papa iṣire MKO Abiola nilu Abẹokuta lati pade aarẹ Buhari ni awọn eeyan kan ti ọpọ gbagbe pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan ṣa dede bẹrẹ si ni le awọn ololufẹ oludije ipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC, Dapọ Abiọdun kuro ni ori ijoko wọn.
Iroyin sọ pe awọn janduku naa bẹrẹ si nii lọ kaakiri ijoko ni papa iṣire naa ti wọn si n le awọn ti wọn ba funra si pe wọn jẹ ololufẹ Dapọ Abiọdun kuro ni aye wọn.

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad
Nṣe lawọn eeyan naa n sare gun ori odi ti wọn mọ yii papa iṣire naa ka lati sa asala fun ẹmi wọn.
Iroyin sọ pe, oniruuru ohun ija bii apola igi ati ogun abẹnugọngọ ni awọn janduku naa ko da ni ti wọn si n kọlu ẹnikẹni ti wọn ba ri to wọ aṣọ alawọ rẹsurẹsu , iyẹn awọ ti wọn mọ mọ awọn ololufẹ Dapọ Abiọdun, oludije ipo gomina ni ipinlẹ Ogun.
Nṣe ni wọn fara gbọgbẹ loriṣiriṣi lasiko ti wọn fi n gbiyanju lati sa asala fun ẹmi wọn.
Nitori ati yẹra fun ikọlu awọn janduku naa, nṣe ni gbogbo wọn n bọ aṣọ ti wọn wọ gbogbo to ni ami idanimọ Dapọ Abiọdun lara









