Ó tó káwọn ẹ̀ṣọ́ àbò ìpínlẹ̀ máa lo ìbọn ìgbàlódé lóòtọ́, ìkọlù sílẹ̀ Yorùbá kọjá àlà - Afenifere

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀ Yorùbá ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn agbéṣùmọ̀mí kan ṣe wọ aṣọ iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà láti fi ṣe ìkọlù sí àwọn ènìyàn kan ní ìlú Ipapo, Oke Ogun, ìpínlẹ̀ Oyo.
Níbi ìkọlù ọ̀hún ni ìròyìn ní àwọn mẹ́rin ni agbébọn náà jí gbé lọ.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ Afenifere Jare Ajayi fi síta ní bí àwọn agbéṣùmọ̀mí ṣe ṣèkọlù ọ̀hún tí wọ́n sì rí bi sálọ tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tí àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ dá sílẹ̀ ní láti máa lo ìbọn gidi.
Ajayi ní pẹ̀lú àwọn ìkọlù sí ilẹ̀ Yorùbá èyí tó ń wáyé ní lemọ́lemọ́ yìí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò abẹ́lé nílò láti máa ṣàmúlò ìbọn ìgbàlódé láti kojú àwọn ọ̀daràn náà.
Ó ní ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹwàá ọdún 2022 ni àwọn agbébọn bíi mẹ́wàá ya wọ oko ènìyàn kan níbi tí àwọn àgbẹ̀ mẹ́rìnlá ti ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n sì jí àwọn mẹ́rin gbé lọ nínú wọn nígbà tí àwọn mẹ́wàá móríbọ́.
Ó tẹ̀síwájú pé òṣìṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ aláàbò Amotekun kan ní lásìkò tí àwọn fi dé ibi tí àwọn ajínigbé náà ti ń ṣọṣẹ́ lọ́wọ́ ṣùgbọ́n àwọn kò le dá ààbò àwọn ti wọ́n jí gbé náà nítorí ìbọn AK47 ni àwọn gbé dání tó sì jẹ́ wí pé ṣakabùlà ló wà lọ́wọ́ àwọn.
Ajayi wòye wí pé tó bá jẹ́ wí pé ìbọn ìgbàlódé ló wà lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò Amotekun ọ̀hún ó ṣeéṣe kí àwọn agbébọn náà má ri iṣẹ́ burúkú wọn ṣe tó bẹ́ẹ̀ nítorí pẹ̀lú ìbọn ṣakabùlà ọwọ́ wọn, wọ́n ṣì jà fitafita láti kojú àwọn agbébọn náà.

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ó fi kún un pé alága àwọn àgbẹ̀ ní agbègbè náà ní aṣọ iléeṣẹ́ ológun ni àwọn agbébọn náà wọ̀ wá láti fi ṣe iṣẹ́ láabi wọn.
Ajayi ní ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún àwọn pé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta bákan náà ni agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun, Yemisi Opalola kéde pé àwọn rí òkú Olóyè Oladepo Asaolu, Babaloja ti ìlú Ora-Igbomina, ìjọba ìbílẹ̀ Oke-Ila ìpínlẹ̀ náà nínú igbó kan.
Ó ní ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹwàá ni àwọn ajínigbé jí olóyè náà gbé nínú oko rẹ̀ kí wọ́n tó rí òkú rẹ̀ náà.
Bákan náà ló ní yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí, Ajayi ní bí àwọn ajínigbé ṣe jí Ọba Owa-Onire, ìyàwó àti awakọ̀ rẹ̀ gbé ní ìpínlẹ̀ Kwara láìpẹ́ yìí jẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń kan àwọn lóminú.
Báwo ni àwọn agbébọn ṣe ń rí aṣọ iléeṣẹ́ ológun àtàwọn ìbọn tí wọ́n ń lò?
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí Ajayi fi síta ṣe sọ, ó ní ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń bèèrè pé báwo ni àwọn agbébọn àti agbéṣùmọ̀mí wọ̀nyí ṣe ń rí àwọn ìbọn ìgbàlódé tí wọ́n ń lò láti fi ṣọṣẹ́.
Ajayi tẹ̀síwájú pé bí ìjọba àpapọ̀ ṣe kọtí ọ̀gbọin sí ìpè àwọn gómìnà, ẹgbẹ́ bíi Afenifere àtàwọn mìíràn tó ń pè fún ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ àti ti ẹsẹ̀ kùkú jẹ́ ohun tíkò dára tó.
Ó fi kún un pé lọ́pọ̀ ìgbà ni gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu, gómìnà ìpínlẹ̀ Benue Samuel Ortom àtàwọn mìíràn káàkiri Nàìjíríà ti ń bẹ ìjọba àpapọ̀ láti fi àyè gba àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tí wọ́n dá sílẹ̀ láti máa lo ìbọn ìgbàlódé.
ó ní tó bá jẹ́ wí pé ìjọba fàyè gba àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láyè láti máa lo ìbọn ìgbàlódé àwọn ọ̀daràn kò ní kàn máa ya wọ ìlú láti hu ìwà kò tọ́.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ní tí ìjọba Buhari bá fẹ́ rẹ́yìn ìpèníjà ààbò gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń sọ, ó ní ó gbọ́dọ̀ fàyè gba ọlọ́pàá ìpínlẹ̀, gba àwọn ìṣèjọba tòótọ̀ láyè, kí wọ́n sì fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ní ohun ìjà gidi láti ṣe iṣẹ́ wọn bó ṣe tọ́.















