Ẹ yé tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀ EFCC, ẹ kó láṣẹ láti fòfin gbé wa - àwọn aṣòfin Oyo sí EFCC

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo àti EFCC

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu ní orílẹ̀ èdè yìí, EFCC ṣe ránṣẹ́ sí àwọn aṣòfin ilé náà láti yọjú sí ọ́fíìsì wọn.

Ní ọdún 2021 ni EFCC ti ṣaájú ránṣẹ́ pé àwọn alákòóso ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà láti wá wí tẹnu wọn lórí bí wọ́n ṣe ná bílíọ̀nù kan náírà láti fi ra ọkọ̀ fún àwọn aṣòfin.

Ìgbésẹ̀ yìí ló mú kí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ọ̀hún, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2022, wọ EFCC lọ sí ilé ẹjọ́ pé àjọ náà kò ní ẹ̀tọ́ kankan láti ṣèwádìí bí ilé náà ṣe ń ná owó rẹ̀.

Nínú ẹjọ́ tí Agbẹjọ́rò ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Oyo, Musibau Adetunbi pè ni wọ́n ti sọ pé lábẹ́ abala 125 ìwé òfin ilẹ̀ Nàìjíríà, EFCC kò ní ẹ̀tọ́ láti máa tojú bọ ìwé owó àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀.

Wọ́n ní olúyẹ̀wé owó wò àgbà ìpínlẹ̀ Oyo ìyẹn Auditor General nìkan ló ní ẹ̀tọ́ láti yẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin lọ́wọ́ wò lórí bí wọ́n ṣe ń ná owó wọn.

Nígbà tó ń gbé ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ kalẹ̀ nígbà náà, Adájọ́ Uche Agomoh ti ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìlú Ibadan ní EFCC kò ní ẹ̀tọ́ láti yẹ àwọn aṣòfin náà lọ́wọ́ wò.

Nínú èsì àjọ EFCC wọ́n ní ìdájọ́ tí Adájọ́ Agomoh gbé kalẹ̀ yìí kó tẹ̀ àwọn lọ́rùn tí wọ́n sì mórílé ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

Ní ọjọ́ Keje oṣù Kẹwàá ni EFCC gbé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Oyo lọ sí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn.

EFCC tún ránṣẹ́ sí Abẹnugan ilé àtàwọn míì láìpẹ́ yìí

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Láìpẹ́ yìí ni àjọ EFCC tún ránṣẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ ilé náà láti tún wá wí tẹnu wọn lórí ìwádìí èyí tí wọ́n ń ṣe kan.

Ẹ̀wẹ̀, akọ̀wé ilé, Yetunde Oludara Awe nínú ìwé àkọránṣẹ́ kan tó fi ránṣẹ́ sí EFCC ní kò yẹ kí àjọ EFCC máa tẹ òfin ilé ẹjọ́ lójú mọ́lẹ̀.

Awe ní kò sí aṣòfin kankan tó máa yọjú sí ọ́fíìsì EFCC nítorí ọ̀rọ̀ àwọn méjéèjì ti wà ní ilé ẹjọ́ àti pé tó sì yẹ kí àwọn bọ̀wọ̀ fún òfin láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀.

Ó ní ó dìgbà tí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, tí EFCC gbé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà lọ, bá gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ ní àwọn tó lè mọ̀ bóyá àwọn aṣòfin náà máa yọjú sí EFCC tàbí bẹ́ẹ̀kọ́.

Awe wá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé pẹ̀lú bí EFCC ṣe ti gba ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lọ kò yẹ́ kí àjọ náà tún máa kọ̀wé ránṣẹ́ sí àwọn aṣòfin tó fi mọ́ abẹnugan ilé, Ade Edward Ogundoyin láti wá wí tẹnu wọn mọ́.

Bákan náà ló rán àjọ EFCC létí pé wọ́n ti tọwọ́ bọ ìwé pé gbogbo òfin àti ìlànà ilé ẹjọ́ ni àwọn máa tẹ̀lé lórí ẹjọ́ náà.

Ó fi kun pé ó tilẹ̀ jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn pé EFCC le máa kọ̀wé ránṣẹ́ sí àwọn aṣòfin nígbà tó jẹ́ wí pé àwọn ni agbẹjọ́rò tó ń ṣojú àwọn nílé ẹjọ́.

Ó ní gbogbo ohun tí àjọ náà bá fẹ́ bá àwọn sọ ni kí wọ́n máa fi ṣọwọ́ sí agbẹjọ́rò àwọn láti àsìkò yìí lọ nítorí òun ni aṣojú àwọn nílé ẹjọ́.

Awe tún làá mọ́lẹ̀ pé kò sí ẹni tó ga ju òfin lọ nínú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àti EFCC nítorí náà ní ṣe ló yẹ kí àwọn fi àyè gba òfin láti jẹ́ olùtọ̀nà láàárín àwọn méjéèjì.