Ọlọ́pàá tú ọkùnrin ẹni ọdún 67 tí wọ́n dè mọ́lẹ̀ nínú yàrá fún ogún ọdún sílẹ̀

Aworan ẹni ti wọn de mọle fun ogun ọdun

Oríṣun àwòrán, Tribune Online

Ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin kan, Ibrahim Ado, ti wọn ti mọ inu yara fun ogun ọdun ti gba itusilẹ niluu Kaduna.

Awọn oṣiṣẹ to n ri si imọtoto ayika lo kọkọ ṣawari ọkunrin naa ninu yara ti wọn tii mọ ladugbo Benin, ni Kaduna, lọjọru.

Agbẹnusọ awọn eeyan naa ti ko fẹ ki awọn akọroyin fi orukọ oun lede sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ iyalẹnu fun awọn.

O ni “Lonii, a wa sinu ile yii lati ṣawari awọn ounjẹ ti wọn ko pamọ amọ ti wọn ko tọju daadaa ni a ri ọkunrin naa ni ihoho ti wọn de mọlẹ ninu yara kan.”

“A ri pe ipo to wa ko dara, oorun to si n jade lati inu yara naa buru jai.”

“Lẹyin naa ni a ja yara naa ti a si gbe jade, amọ ṣe ni ọkunrin n ṣe bii ẹranko, igba yẹn ni a to mọ pe o ti to ogun ọdun ti wọn ti tii mọ yara naa.”

O fi kun pe inu yara ọhun lo ti n jẹun, ibẹ naa lo n ṣe igbọnsẹ si.

Lẹyin naa ni wọn ke si ileeṣẹ ọlọpaa lati wa gbe kuro nibẹ.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori bi ọrọ naa ṣe jẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọhun, Mohammed Jalige sọ fun awọn akọroyin pe awọn ti fi iwe pe eeyan marun un ninu ile ti wọn ti ri ọkunrin naa lati wa sọ ohun ti wọn mọ nipa bi ọrọ naa ṣe jẹ.