Fani-Kayode, Keyamo sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Atiku tó ní òun ni ipò Ààrẹ yẹ bíi ọmọ Ariwa tó fẹ́ràn Naijiria

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, @atiku

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti bu ẹnu atẹ lu oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, lẹyin to ni oun lo yẹ ki awọn eeyan Ariwa dibo fun dipo awọn oludije lati ilẹ Yoruba tabi ilẹ Igbo.

Lara awọn to n sọko ọrọ si Atiku ni minisita tẹlẹ fun eto irina ofurufu, Femi Fani-Kayode, ati agbẹnusọ fun ikọ ipolongo ibo fẹgbẹ oṣelu APC, amofin Festus Keyamo.

Bi Keyamo ṣe n sọ pe asiko ti to fun Atiku lati yọwọ ninu eto idibo naa ni Fani-Kayode n sọ pe ọrọ itiju gbaa ni Atiku sọ.

Ki ni Atiku sọ?

Asiko ti Atiku n dahun awọn ibeere kan lo sọ ọrọ naa nibi ifọrọwerọ pẹlu alaga ẹgbẹ awọn agbagba Ariwa, Northern Elders Forum, NEF, Hakeem Baba-Ahmed, niluu Kaduna.

Atiku sọ pe oun lo yẹ ki awọn eeyan Ariwa dibo fun nitori pe oun jẹ ọmọ Ariwa to ni ifẹ Naijiria lọkan.

O ni “Ohun ti awọn ara Ariwa nilo ree, wọn ko nilo ọmọ Yoruba tabi Igbo, mo duro niwaju yin gẹgẹ bii ẹni to fẹran Naijiria to si wa lati Ariwa.”

Amọ ọrọ naa ko dun mọ awọn eeyan kan nminu.

Femi Fani-Kayode fesi

Ninu awọn atẹjade kan loju opo Twitter rẹ, Fani-Kayode sọ pe awọn ko ni gba ki Atiku ṣe ohun to ṣe fun gomina ipinlẹ Rivers, Nyemsom Wike, ṣaaju ati lẹyin eto idibo abẹnu ẹgbẹ wọn fun awọn ọmọ Naijiria.

O ni “Ọrọ ti Atiku sọ yii ko ṣe itẹwọgba, o si jẹ eyii to n dojuti ni.”

“Idi ni pe ti yoo ba fi di ọdun to n bọ, a o ti ni Aarẹ to ti lo ọdun mẹjọ lori alefa, to si jẹ ọmọ iha Ariwa.”

“Amọ ṣa, ọpọ eeyan ni Ariwa ni ko ronu bii ti Atiku atawọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ṣe n ronu, nitori wọn ko ri awọn eeyan guusu bii ẹru.”

“Akoko ti to ki agbara kuro ni Ariwa lọ si Guusu, ọpọ eeyan to wa loke ọya atawọn eeyan Ariwa ninu ẹgbẹ oṣelu APC lo si gba bẹẹ.”

Ohun ti Keyamo sọ

Nigba ti yoo sọrọ ni tirẹ, agbẹnusọ ipolongo APC, Festus Keyamo ke si Atiku Abubakar lati yọwọ lawo ere je ipo Aarẹ naa nitori ohun to sọ.

O ni o ṣe ni laanu pe Atiku lo ọrọ ẹlẹyamẹya lati ṣe ipolongo ki awọn eeyan le dibo fun.

Keyamọ pari ọrọ rẹ pe oju gba oun ti fun Atiku fun ọrọ to jade lati ẹnu rẹ, ko si yẹ ko kopa ninu eto idibo naa mọ.