Wo àtúnṣe òpópónà tíjọba fẹ́ ná ₦248bn lé lórí lọ́dún 2023

Oríṣun àwòrán, Ministry of Works & Housing nigeria
Ojilelugba o le mẹjọ biliọnu Naira ni ijọba apapọ Naijiria ti ya sọtọ bayii fun ṣiṣe awọn opopona tuntun ati titun awọn to wa nilẹ ṣe kaakiri orilẹede Naijiria.
Eyi jẹyọ ninu atupalẹ aba eto iṣuna fun ọdun 2023 ti aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari gbe kalẹ niwaju ileegbimọ aṣofin apapọ ljọ Ẹti.
Aarẹ Buhari ṣalaye ninu ọrọ apilẹkọ to ka niwaju awọn aṣofin apapọ lọjọ naa pe iṣẹ ti pọ to ti waye lori titun awọn ọna to bajẹ ṣe ati ṣiṣe awọn opopona tuntun.
Lara awọn opopona to darukọ ni opopona marosẹ Eko si Ibadan, opopona marosẹ Abuja si Kaduna si Kano pẹlu opopona marosẹ to so ẹkun ila oorun ati iwọ orun pọ ni Niger Delta.
Bakan naa lo ṣalaye pe oun nireti pe nigba ti saa oun yoo ba fi pari lọdun 2023, iṣẹ yoo ti pari lori awọn opopona naa.
Lara awọn opopona ti wọn yoo pari ni atunṣe opopona Ikorodu si Shagamu, opopona onibeji Abuja si Keffi, sisọ opopona Keffi si Akwanga si lafia si Makurdi nipinlẹ Nasarawa ati Benue di onibeji.
Opopona Enugu si Otukpo si Makurdi ni ipinlẹ Enugu ati Benue ni owo ti iye rẹ to biliọnu mejilelọgbọn abọ naira (₦32.5bn).

Oríṣun àwòrán, Ministry of Works & Housing Nigeria
Awọn opopona miran ti ọrọ tun kan ni atunṣe opopona Keffi si Akwanga si Lafia pẹlu biliọnu mọkanlelọgọrun (N101.1bn).
Pipari afara Chanchangi lopopona Takum-Wukari nipinlẹ Taraba pẹlu ọgọrun miliọnu Naira (₦100m).
Siso oju ọna Jattu si Fugar si Agenebode di onibeji pẹlu atunṣe ọna Irekpa si Fugar si Agenebode ni ipinlẹ Edo pẹlu igba o le aadọta miliọnu naira (₦250m).
Bakan naa ni ijọba apapọ tun ya irinwo miliọnu Naira, N400m sọtọ fun ṣiṣe opopona Bidda si Sacci si Nupeko ati afara Nupeko/Patigi lori odo River Naiger to so Nupeko ati Patigi nnipinlẹ Niger ati Kwara.

Oríṣun àwòrán, Ministry of Works & Housing nigeria
Bakan naa ni ijọba yoo se atunṣe oju ọna Maiduguri si Monguno, ti yoo na ijọba lowo to to igba o le aadọta miliọnu naira, (₦250m).
Atunṣe opopona Wukari/Akwana ni ipinlẹ Taraba yoo si gba aadọjọ miliọnu naira (₦150m).
Igba ati aadọta miliọnu naira, (₦250m) ni wọn ya sọtọ fun opopona Igboho Oloko si Agbonle.
Opopona Damaturu si Biu ni ipinlẹ Yobe ati Borno yoo na ijọba ni ọọdunrun miliọnu naira (₦300bn) ati kikọ afara aala ajumọni ni Mfum/Ekok.

Oríṣun àwòrán, Federal Ministry of Works & Housing
Awọn akanṣe iṣẹ miran ti ijọba apapọ tun la kalẹ ni sisọ oju ọna Ọbajana junction si Benin (Okene-Auchi) fun biliọnu marun un (₦5bn).
Atunṣe opopona Apapa si Oworonṣoki si Ọjọta, atunṣe Ilọrin si Kabba si Obajana nipinlẹ Kwara si Kogi pẹlu irinwo miliọnu Naira.
Nigba to n fesi, ọga agba ajọ fun itẹsiwaju sisọ ileeṣẹ di ti aladani ni Naijiria, Muda Yusuf woye pe iye owo wọnyi kere.
Ni iwoye rẹ, triliọnu kan naira (₦1trillion) ni owo to yẹ ki wọn maa ya sọtọ fun atunṣe ọna lọdọọdun lorilẹede Naijiria.












