Bí Adeleke bá lé àwọn alága ìbílẹ̀ tuntun, ilé aṣòfin yóò yọ òun náà nípò gómìnà - APC Osun

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gomina tuntun ti wọn sẹsẹ dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ni wọn ti se ikilọ fun pe ko ma gbiyanju lati yọ awọn alaga ijọba ibilẹ ti wọn sẹsẹ dibo yan nipinlẹ naa.
Ikilọ naa lo waye latẹnu agbẹjoro ẹgbẹ oṣelu APC, Adegoke Ogunsola, nigba to danu ibeere lẹyin ti eto idibo awọn alaga ibilẹ to waye lopin ọsẹ.
Bakan naa ni Ogunsola salaye pe bi Adeleke ko ba fẹ kile asofin ipinlẹ naa gbe igbesẹ lati yọ oun fura rẹ nipo gomina, ko gbọdọ fọwọ kan awn alaga ijọba ibilẹ tuntun naa.
Eto idibo alaga ibilẹ naa ni ẹgbẹ oṣelu PDP bu ẹnu atẹlu pe ko ba ofin mu, to si leri pe oun yoo yọ awọn alaga naa nipo ni kete ti gomina tuntun ba ti ṣe ibura wọle.
Sugbọn Ogunsola, ẹni to jẹ oludije sipo alaga ni ijọba ibilẹ Ifelodun ni ko si ijọba kankan ni Naijiria to ni ẹtọ lati tu awọn alaga ti wọn dibo yan ka.
"Ile gbimọ asofin nipinlẹ lo tun le tu awn alaga ijba ibilẹ ka"
Amofin naa ni ijọba ibilẹ ni ọkan lara ijọba mẹta, ti ko ki n ṣe pe ijọba ipinlẹ lo yan wọn gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ.
“Gomina ipinlẹ ko ni agbara lati tu awọn alaga ti ilu dibo yan ka , ayafi ti ileẹjọ ba fun ni agbara naa nitori idi kan tabi ikeji.
Awọn miiran to le tu awọn alaga ijọba ibilẹ ka ni Ile gbimọ asofin nipinlẹ naa.”
Ogunsola ni ẹṣẹ to le yọ Adeleke nipo gẹgẹ bii Gomina, ni ti Gomina tuntun naa ba gbiyanju lati tu awọn alaga ijọba ibilẹ ka.
A tu awọn alaga tuntun naa ka ni ilana ofin Naijiria - PDP
Nigba ti alaga igbimọ alakoso fidihẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun, Akindele Adekunle sọrọ lasiko ijiroro kan pẹlawọn oniroyin, o ni ọgbọn ni ijọba ipinlẹ Ọṣun n da lati da ewe bo awọn iwa ijẹkujẹ to ti hu silẹ.
Bakan naa lo ke si ọga agba patapata ileeṣẹ ọlọpaa ati kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ ọhun pe ki wọn tete gbe igbesẹ to yẹ, lati dena eefin wahala to n ru naa. ko to di ina rogbodiyan ti yoo tigi boju alaafia nipinlẹ naa waye..
Adekunle ninu atẹsita to fi fesi idunkoko ẹgbẹ oṣelu APC ni awọn yoo tu awọn alaga naa ka ni ilana ofin orilẹede Naijiria .















