Àṣírí afurasí ayédèrú Dókítà tú, àwọn aláṣẹ pariwo síta

Oríṣun àwòrán, KATH PR UNIT
Awọn Aláṣẹ ile iwosan kan lorilẹede Ghana ti mu afurasi ayederu dokita kan ni agbegbe ile wosan naa.
Afurasi ọhun ni ọwọ tẹ pẹlu aṣọ dokita lasiko ti wọn le e kuro ni Ile iwosan Komfo Anokye lọjọ Aje.
O ni orukọ oun ni Dokita William Cyril Cohen ṣùgbọ́n ko le ṣàlàyé ibi to ti kawe gba oye ati igba to pari ẹkọ rẹ.
Awọn Aláṣẹ ni awọn ko mọ orukọ, ti ko si ki n ṣe dokita ni ile iwosan Komfo Anokye.
Kete ti ọwọ tẹ afurasi Dokita yii ni wọn ránṣẹ́ pe Ileeṣẹ ọlọpaa ni Kumasi, ti wọn si fa le wọn lọwọ.
Fọnran to n lọ kiri lori Ayelujara
Fọnran kan to ti gba ori ayelujara ṣafihan bi ọpọ eeyan ṣe wa ni ayika ọkunrin kan lẹyin ti ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ.
Awọn eeyan n ki gbe le e lori pe ayederu dokita ni, ti awọn mii si n bere ibeere lọwọ rẹ ṣugbọn o kọ lati fesi.
Agbẹnusọ ile iwosan KAFH, Kwame Frimpong sọ fun BBC pe ọkan lara awọn oludari ile iwosan naa lo ṣawari ọkunrin ọhun nibi to ti n fi ẹse gba ilẹ kiri ni agbala ile iwosan naa.
Lẹyin ti wọn bii pe ki lo n wa kiri, ọkunrin naa fesi pe oun kan n kọja lọ ni.
Kete to sọ eyi ni o pariwo sita, ti ọkunrin naa si bẹrẹ si maa sara.
“A le ọkunrin naa, ti ọwọ wa si tẹ ẹ. Awọn ẹsọ ile iwosan bere awọn ibeere lọwọ rẹ ṣugbọn ko le fesi.”
Nje ṣe ayederu dokita yii fun awọn alaarẹ ni itọju?
Lẹyin ti ọwọ tẹ ayederu dokita naa, iroyin ofege bẹrẹ si ni maa lọ kiri pe o ṣeeṣe ki ayederu dokita naa ti fun awọn alaarẹ ni ile wosan naa ni itọju.
Sugbọn Kwame Frimpong ni ọrọ ko ri bẹẹ.
“Ayederu dokita ko ni anfani si ibi ti awọn alaarẹ wa, ti ko si le ṣe itọju fun wọn rara.
“Ko si ẹni to le pelo ogun fun awọn eeyan, ti ko ba si orukọ ni iwe akọsilẹ wa,”
Eyi kọ ni igba akọkọ ti irufẹ isẹlẹ yii yo waye ni ile wosan naa.
Frimpong ni ko sẹyin bi ero ṣe ma n pọ nile iwosan naa ti awọn si n gbiyanju lati ko awọn kuro lọ si ile iwosan ti wọn.















