Iṣẹ́ dókítà ló wù mí àmọ́ mo di Elékuru láti ran òbí mi lọ́wọ́ – Kehinde Elekuru

Àkọlé fídíò, Kehinde Ahmed: Èdè Lárúbáwá ni mò ń kọ́ báyìí láti lọ fi kọ́ṣẹ́ dókítà ní Egypt
Iṣẹ́ dókítà ló wù mí àmọ́ mo di Elékuru láti ran òbí mi lọ́wọ́ – Kehinde Elekuru

Yoruba ni ori lo mọ isẹ asela, bẹẹ si ni ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo kọkọ tiirin.

Oniruuru ọna si ni ẹda le ba goke nitori kii se gbogbo eeyan ni wọn bi pẹlu owo ati la.

Kii se pe o wu Kehinde Ahmed lati maa kiri Ekuru kiri igboro ilu Ilorin amọ aanu mama rẹ lo se e, ẹni to n gbe ọmọ tuntun lọwọ nigba ti wọn bẹrẹ owo naa.

Nigba ti BBC Yoruba se alabapade ọdọkunrin to ti balaaga naa, to si baafu mọri, lati fi ta ekuru, se ni ẹnu ya wa lati mọ ohun to gbe de ibẹ.

Kehinde Ahmed n kiri Ekuru

Kí ló sún Kehinde Ahmed de ibi ekuru tita?

Nigba to n ba wa sọrọ, Kehinde ni ọrẹ iya oun to n fi ilu Ilorin silẹ lo n ta ekuru amọ se lo gba mama oun niyanju lati bẹrẹ okoowo naa nitori o maa n ya lati ta.

Lasiko naa, Kehinde ni mama oun sẹsẹ bimọ ni, yoo si nira fun lati maa kiri ekuru, idi si ree ti oun ati ekeji oun fi pinnu lati ran lọwọ nidi isẹ naa.

O si ni o ti to ọdun mẹwa ti awọn ti bẹrẹ isẹ naa.

"Maa lọ si Egypt lati lọ kọ isẹ dokita pẹlu ede Larubawa"

Nigba to n salaye ohun to fẹ fi ọjọ ọla rẹ se, Kehinde olounjẹ, gẹgẹ bi awọn onibara rẹ ti maa n pe sọ pe, isẹ dokita lo wu oun lati se amọ oun ko gba maaki to yẹ lati wle sile ẹkọ fasiti lati kọ isẹ naa.

O fikun pe lọwọ lọwọ bayii, oun ti n kọ ede Larubawa mọ ekuru ti oun n ta eyi ti yoo wulo fun oun lati fi kọ isẹ dokita lorilẹede Egypt.

Kehinde Ahmed n ro ẹfọ

“Ọpọ iwọsi ni oju mi n ri tori pe mo n ta ekuru”

Kehinde wa n fi ika hanu pe oju oun ti ri ọpọ iwọsi nidi bi oun se n kiri ekuru kiri.

O ni ati ọmọde, ati agba lo n fi iwọsi lọ oun nitori pe oun n kiri ekuru, ti wọn yoo si maa pariwo Kehinde olounjẹ.

Bakan naa lo ni wọn maa n tẹnubọlẹ pe oun ko lọ wa isẹ kọ lai mọ pe bi Oluwa se kọ ni.

Kehinde wa gba awọn akẹẹgbẹ rẹ to jẹ ọdọ nimọran lati maa ran awọn obi wọn lọwọ ni gbogbo ọna.